FILIPI 4:17-19

FILIPI 4:17-19 YCE

Kì í ṣe ẹ̀bùn ni mò ń wá, ṣugbọn mò ń wá ọpọlọpọ èso fún anfaani yín. Ìwé ẹ̀rí nìyí fún ohun gbogbo tí ẹ fún mi, ó tilẹ̀ ti pọ̀jù. Mo ní ànító nígbà tí mo rí ohun tí ẹ fi rán Epafiroditu sí mi gbà. Ó dàbí òróró olóòórùn dídùn, bí ẹbọ tí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà, tí inú Ọlọrun dùn sí. Ọlọrun mi yóo pèsè fún gbogbo àìní ẹ̀yin náà, gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ ọrọ̀ rẹ̀ tí ó lógo nípasẹ̀ Jesu Kristi.