Lágbára Oluwa, mò ń gbèrò ati rán Timoti si yín láì pẹ́, kí n lè ní ìwúrí nígbà tí mo bá gbúròó yín. N kò ní ẹlòmíràn tí ó dàbí rẹ̀ tí ọkàn wa rí bákan náà, tí ó sì tún ń fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣe àwọn nǹkan tí ó bá jẹ mọ́ tiyín. Nítorí nǹkan ti ara wọn ni gbogbo àwọn yòókù ń wá, wọn kò wá nǹkan ti Jesu Kristi. Ṣugbọn ẹ mọ bí Timoti ti wúlò tó, nítorí bí ọmọ tíí ṣe pẹlu baba rẹ̀ ni ó ń ṣe iṣẹ́ iranṣẹ pẹlu mi ninu iṣẹ́ ìyìn rere. Nítorí náà, òun ni mo lérò pé n óo rán nígbà tí mo bá mọ bí ọ̀rọ̀ mi yóo ti já sí. Ṣugbọn mo ní igbẹkẹle ninu Oluwa pé èmi fúnra mi yóo wá láìpẹ́. Mo kà á sí pé ó di dandan pé kí n rán Epafiroditu pada si yín. Ó jẹ́ arakunrin mi, alábàáṣiṣẹ́ pẹlu mi, ati ọmọ-ogun pẹlu mi. Ó tún jẹ́ òjíṣẹ́ ati aṣojú yín tí ó ń mójútó àìní mi.
Kà FILIPI 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: FILIPI 2:19-25
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò