MATIU 5:1-6

MATIU 5:1-6 YCE

Nígbà tí Jesu rí ọ̀pọ̀ eniyan, ó gun orí òkè lọ. Ó jókòó; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ń kọ́ wọn pé: “Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó jẹ́ òtòṣì ní ẹ̀mí, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, nítorí Ọlọrun yóo tù wọ́n ninu. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀, nítorí wọn yóo jogún ayé. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ebi òdodo ń pa, tí òùngbẹ òdodo sì ń gbẹ, nítorí Ọlọrun yóo bọ́ wọn ní àbọ́yó.

Àwọn fídíò fún MATIU 5:1-6