Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ó jókòó láti jẹun pẹlu àwọn mejila. Bí wọ́n ti ń jẹun, ó wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ọ̀kan ninu yín yóo fi mí fún àwọn ọ̀tá.” Ọkàn wọn dàrú pupọ; ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ń bèèrè pé, “Kò sá lè jẹ́ èmi ni, Oluwa?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹni tí ó ń fi òkèlè run ọbẹ̀ ninu àwo kan náà pẹlu mi ni ẹni náà tí yóo fi mí fún àwọn ọ̀tá. Ọmọ-Eniyan ń lọ gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ gbé! Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i.” Nígbà náà ni Judasi, ẹni tí ó fi í fún àwọn ọ̀tá, bi í pé, “Àbí èmi ni, Olùkọ́ni?” Jesu dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ sọ ọ́.” Nígbà tí wọn ń jẹun, Jesu mú burẹdi, ó gbadura sí i, ó bù ú, ó bá fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; ó ní, “Ẹ gbà, ẹ jẹ ẹ́, èyí ni ara mi.” Nígbà tí ó mú ife, ó dúpẹ́, ó fi fún wọn, ó ní “Gbogbo yín ẹ mu ninu rẹ̀. Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí a fi dá majẹmu, ẹ̀jẹ̀ tí a ta sílẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ eniyan. Mo sọ fun yín, n kò ní mu ọtí èso àjàrà mọ́ títí di ọjọ́ náà tí n óo mu ún pẹlu yín ní ọ̀tun ní ìjọba Baba mi.”
Kà MATIU 26
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: MATIU 26:20-29
8 Days
The final week in the life of Jesus was no ordinary week. It was a time of bittersweet goodbyes, lavish giving, cruel betrayals and prayers that shook heaven. Experience this week, from Palm Sunday to the miraculous Resurrection, as we read through the Biblical account together. We will cheer with the crowds on Jerusalem’s streets, shout in anger at Judas and the Roman soldiers, cry with the women at the Cross, and celebrate as Easter morning dawns!
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò