Wọn á di ẹrù wúwo, wọn á gbé e ka àwọn eniyan lórí, bẹ́ẹ̀ ni àwọn fúnra wọn kò sì jẹ́ fi ọwọ́ wọn kan ẹrù náà. Gbogbo ohun tí wọn ń ṣe, wọ́n ń ṣe é kí eniyan lè rí wọn ni. Wọn á di tírà pàlàbà-pàlàbà mọ́ iwájú. Wọn á ṣe waja-waja ńláńlá sí etí aṣọ wọn. Wọ́n fẹ́ràn ìjókòó ọlá níbi àsè. Wọ́n fẹ́ràn àga iwájú ní ilé ìpàdé. Wọ́n fẹ́ràn kí eniyan máa kí wọn láàrin ọjà ati kí àwọn eniyan máa pè wọ́n ní ‘Olùkọ́ni.’ Ṣugbọn ẹ̀yin ní tiyín, ẹ má jẹ́ kí wọ́n pè yín ní ‘Olùkọ́ni,’ nítorí ẹnìkan ṣoṣo ni olùkọ́ni yín; arakunrin ni gbogbo yín jẹ́. Ẹ má pe ẹnìkan ní ‘Baba’ ní ayé, nítorí ẹnìkan ṣoṣo ni Baba yín, ẹni tí ó wà ní ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni pè yín ní ‘Ọ̀gá,’ nítorí ọ̀gá kanṣoṣo ni ẹ ní, òun ni Mesaya. Ẹni tí ó bá lọ́lá jùlọ láàrin yín ni kí ó ṣe iranṣẹ yín. Ẹni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óo rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óo gbé ga.
Kà MATIU 23
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: MATIU 23:4-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò