MATIU 22:42-45

MATIU 22:42-45 YCE

“Kí ni ẹ rò nípa Mesaya, ọmọ ta ni?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ọmọ Dafidi ni.” Ó bá tún bi wọ́n pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo ni Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe darí Dafidi tí Dafidi fi pe Mesaya ní ‘Oluwa’? Dafidi sọ pé, ‘OLUWA sọ fún Oluwa mi pé: Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí n óo fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di ohun ìtìsẹ̀ rẹ.’ Bí Dafidi bá pè é ní ‘OLUWA’, báwo ni Mesaya ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?”

Àwọn fídíò fún MATIU 22:42-45