MATIU 22:35-40

MATIU 22:35-40 YCE

Ọ̀kan ninu wọn tí ó jẹ́ amòfin, bi í ní ìbéèrè kan láti fi dẹ ẹ́, pé, “Olùkọ́ni, òfin wo ni ó ṣe pataki jùlọ ninu Ìwé Òfin?” Jesu dá a lóhùn pé, “ ‘Fẹ́ Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo ẹ̀mí rẹ, ati ní gbogbo èrò rẹ.’ Èyí ni òfin tí ó ga jùlọ, òun sì ni ekinni. Ekeji fi ara jọ ọ́: ‘Fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí o ti fẹ́ ara rẹ.’ Òfin mejeeji wọnyi ni gbogbo òfin ìyókù ati ọ̀rọ̀ inú ìwé àwọn wolii rọ̀ mọ́.”

Àwọn fídíò fún MATIU 22:35-40