MATIU 17:1-21

MATIU 17:1-21 YCE

Lẹ́yìn ọjọ́ mẹfa, Jesu mú Peteru ati Jakọbu ati Johanu arakunrin Jakọbu, wọ́n lọ sí orí òkè gíga kan; àwọn nìkan wà níbẹ̀. Jesu bá para dà lójú wọn. Ojú rẹ̀ wá ń tàn bí oòrùn. Aṣọ rẹ̀ mọ́ gbòò bí ọjọ́. Wọ́n wá rí Mose ati Elija tí wọn ń bá Jesu sọ̀rọ̀. Peteru bá sọ fún Jesu pé, “Oluwa, kì bá dára kí á máa gbé ìhín. Bí o bá fẹ́, èmi yóo pa àgọ́ mẹta síhìn-ín, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose ati ọ̀kan fún Elija.” Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ìkùukùu kan tí ń tàn bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ohùn kan wá láti inú ìkùukùu náà wí pé, “Àyànfẹ́ ọmọ mi nìyí, inú mi dùn sí i. Ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.” Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́, wọ́n dojúbolẹ̀, ẹ̀rù sì bà wọ́n pupọ. Jesu wá sọ́dọ̀ wọn, ó fọwọ́ kàn wọ́n, ó ní, “Ẹ dìde. Ẹ má bẹ̀rù.” Nígbà tí wọ́n gbé ojú wọn sókè, wọn kò rí ẹnikẹ́ni mọ́, àfi Jesu nìkan. Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jesu pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ má sọ ohun tí ẹ rí fún ẹnikẹ́ni títí a óo fi jí Ọmọ-Eniyan dìde kúrò ninu òkú.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi í pé, “Kí ni ìdí rẹ̀ tí àwọn amòfin fi sọ pé Elija ni ó níláti kọ́kọ́ dé?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Òtítọ́ ni pé Elija yóo wá, yóo sì mú ohun gbogbo bọ̀ sípò. Ṣugbọn mo sọ fun yín, Elija ti dé, ṣugbọn àwọn eniyan kò mọ̀ ọ́n; ohun tí ó wù wọ́n ni wọ́n ṣe sí i. Bẹ́ẹ̀ náà ni Ọmọ-Eniyan yóo sì jìyà lọ́wọ́ wọn.” Ó yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà náà pé nípa Johanu Onítẹ̀bọmi ni ó ń sọ fún wọn. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ àwọn eniyan, ọkunrin kan wá sọ́dọ̀ Jesu, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó ní, “Alàgbà, ṣàánú ọmọ mi, nítorí wárápá a máa gbé e, a sì máa joró pupọ. Nítorí ní ọpọlọpọ ìgbà, a máa ṣubú lu iná; ní ọpọlọpọ ìgbà ẹ̀wẹ̀, a máa ṣubú sinu omi. Mo mú un wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ, ṣugbọn wọn kò lè wò ó sàn.” Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin ìran alaigbagbọ ati ìran tí ó bàjẹ́ yìí, ìgbà wo ni n óo wà lọ́dọ̀ yín dà? Ìgbà wo ni n óo sì fara dà á fun yín dà? Ẹ mú ọmọ náà wá síhìn-ín.” Jesu bá pàṣẹ fún ẹ̀mí èṣù náà kí ó jáde kúrò ninu rẹ̀, ara ọmọ náà sì dá láti ìgbà náà. Nígbà tí ó yá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wá sọ́dọ̀ Jesu níkọ̀kọ̀, wọn bi í pé, “Kí ló dé tí àwa kò fi lè lé ẹ̀mí èṣù náà jáde?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Nítorí igbagbọ yín tí ó kéré ni. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé bí ẹ bá ní igbagbọ tí kò ju wóró musitadi tí ó kéré pupọ lọ, tí ẹ bá sọ fún òkè yìí pé, ‘Kúrò níbẹ̀,’ yóo sì kúrò. Kó ní sí ohun kan tí ẹ kò ní lè ṣe. [ Irú ẹ̀mí burúkú báyìí kò lè jáde àfi nípa adura ati ààwẹ̀.”]

Àwọn fídíò fún MATIU 17:1-21