Ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò Àjọ̀dún Àìwúkàrà tí à ń pè ní Àjọ̀dún Ìrékọjá. Àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ń wá ọ̀nà bí wọn yóo ti ṣe pa Jesu nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan.
Satani bá wọ inú Judasi tí à ń pè ní Iskariotu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila. Ó bá lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili láti bá wọn sọ̀rọ̀ bí ọwọ́ wọn yóo ṣe tẹ Jesu. Inú wọn dùn, wọ́n bá ṣe ètò láti fún un ní owó. Ó gbà bẹ́ẹ̀; ó bá bẹ̀rẹ̀ sí wá àkókò tí ó wọ̀ láti fi Jesu lé wọn lọ́wọ́ lọ́nà tí ọ̀pọ̀ eniyan kò fi ní mọ̀.
Nígbà tí ó di ọjọ́ Àjọ̀dún Àìwúkàrà, ní ọjọ́ tí wọ́n níláti pa ẹran àsè Ìrékọjá, Jesu rán Peteru ati Johanu, ó ní, “Ẹ lọ ṣe ìtọ́jú ohun tí a óo fi jẹ àsè Ìrékọjá.”
Wọ́n bi í pé, “Níbo ni o fẹ́ kí á lọ ṣe ètò sí?”
Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Nígbà tí ẹ bá wọ inú ìlú, ọkunrin kan tí ó ru ìkòkò omi yóo pàdé yín. Ẹ tẹ̀lé e, ẹ bá a wọ inú ilé tí ó bá wọ̀. Kí ẹ sọ fún baálé ilé náà pé, ‘Olùkọ́ni sọ pé níbo ni yàrá ibi tí òun óo ti jẹ àsè Ìrékọjá pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn òun wà?’ Yóo fi yàrá ńlá kan hàn yín ní òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì, tí a ti ṣe lọ́ṣọ̀ọ́. Níbẹ̀ ni kí ẹ ṣe ètò sí.”
Ni wọ́n bá lọ, wọ́n rí ohun gbogbo bí Jesu ti sọ fún wọn. Wọ́n sì tọ́jú gbogbo nǹkan fún àsè Ìrékọjá.
Nígbà tí ó tó àkókò oúnjẹ, ó jókòó láti jẹun pẹlu àwọn aposteli rẹ̀. Ó sọ fún wọn pé, “Ó ti mú mi lọ́kàn pupọ láti jẹ àsè Ìrékọjá yìí pẹlu yín kí n tó jìyà. Nítorí mo sọ fun yín pé n kò tún ní jẹ ẹ́ mọ́ títí di àkókò tí yóo fi ní ìtumọ̀ tí ó pé ní ìjọba Ọlọrun.”
Ó bá mú ife, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó ní, “Ẹ gba èyí, kí ẹ pín in láàrin ara yín. Nítorí mo sọ fun yín pé láti àkókò yìí lọ, n kò tún ní mu ninu èso àjàrà mọ́ títí ìgbà tí ìjọba Ọlọrun yóo fi dé.”
Ó bá mú burẹdi, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bù ú, ó bá fún wọn. Ó ní, “Èyí ni ara mi tí a fun yín. [Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” Bákan náà ni ó gbé ife fún wọn lẹ́yìn oúnjẹ, ó ní, “Ife yìí ni majẹmu titun tí Ọlọrun ba yín dá pẹlu ẹ̀jẹ̀ mi tí a ta sílẹ̀ fun yín.]
“Ṣugbọn ṣá o, ẹni tí yóo fi mí fún àwọn ọ̀tá ń bá mi tọwọ́ bọwọ́ níbi oúnjẹ yìí. Ọmọ-Eniyan ń lọ gẹ́gẹ́ bí ó ti yan ìpín tirẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí yóo fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ gbé!”
Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí wádìí láàrin ara wọn pé ta ni ìbá jẹ́ ninu wọn tí yóo dán irú rẹ̀ wò.
Ìjiyàn kan wà láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé ta ni ó jẹ́ ẹni pataki jùlọ. Jesu sọ fún wọn pé, “Àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè alaigbagbọ a máa jẹ ọlá lórí wọn. Àwọn aláṣẹ wọn ni wọ́n ń pè ní olóore wọn. Ṣugbọn tiyín kò ní rí bẹ́ẹ̀. Ẹni tí yóo bá jẹ́ ẹni tí ó ṣe pataki jùlọ ninu yín níláti dàbí ọmọ tí ó kéré jùlọ. Ẹni tí yóo jẹ́ aṣaaju níláti máa ṣe bí iranṣẹ. Nítorí ta ni eniyan pataki? Ẹni tí ó jókòó tí ó ń jẹun ni, tabi ẹni tí ó ń ṣe iranṣẹ? Mo ṣebí ẹni tí ó ń jẹun ni. Ṣugbọn èmi wà láàrin yín bí ẹni tí ó ń ṣe iranṣẹ.
“Ẹ̀yin ni ẹ dúró tì mí ní gbogbo àkókò ìdánwò mi. Gẹ́gẹ́ bí Baba mi ti fi ìjọba fún mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi náà fi ìjọba fun yín, kí ẹ lè bá mi jẹ, kí ẹ sì bá mi mu ninu ìjọba mi, kí ẹ sì jókòó lórí ìtẹ́ láti máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀yà Israẹli mejila.
“Simoni! Simoni! Ṣọ́ra o! Satani ti gba àṣẹ láti dán gbogbo yín wò, bí ìgbà tí eniyan bá ń fẹ́ fùlùfúlù kúrò lára ọkà. Ṣugbọn mo ti gbadura fún ọ Simoni, pé kí igbagbọ rẹ kí ó má yẹ̀. Nígbà tí ìwọ bá ronupiwada, mu àwọn arakunrin rẹ lọ́kàn le.”
Ṣugbọn Peteru dáhùn pé, “Oluwa, mo ṣetán láti bá ọ wẹ̀wọ̀n, ati láti bá ọ kú.”
Ṣugbọn Jesu dáhùn pé, “Peteru mò ń sọ fún ọ pé kí àkùkọ tó kọ lálẹ́ yìí, ẹẹmẹta ni ìwọ óo sọ pé o kò mọ̀ mí rí!”
Ó wá sọ fún wọn pé, “Nígbà tí mo ran yín níṣẹ́ tí mo sọ fun yín pé kí ẹ má mú àpò owó ati igbá báárà lọ́wọ́, ati pé kí ẹ má wọ bàtà, kí ni ohun tí ẹ ṣe aláìní?”
Wọ́n dáhùn pé, “Kò sí!”
Ó wá sọ fún wọn pé, “Ṣugbọn ní àkókò yìí, ẹni tí ó bá ní àpò owó kí ó mú un lọ́wọ́; ẹni tí ó bá ní igbá báárà, kí òun náà gbé e lọ́wọ́. Ẹni tí kò bá ní idà, kí ó ta ẹ̀wù rẹ̀ kí ó fi ra idà kan. Nítorí mo wí fun yín pé ohun gbogbo tí a ti kọ sílẹ̀ nípa mi níláti ṣẹ, pé, ‘A kà á kún àwọn arúfin.’ Ohun tí a sọ nípa mi yóo ṣẹ.”
Wọ́n sọ fún un pé, “Oluwa, wò ó! Idà meji nìyí.”
Ó sọ fún wọn pé, “Ó tó!”
Jesu bá jáde lọ sórí Òkè Olifi, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Nígbà tí ó dé ibẹ̀ ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ máa gbadura kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò.”
Ó bá kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó lọ siwaju díẹ̀ sí i. Ó kúnlẹ̀, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí gbadura. Ó ní, “Baba, bí o bá fẹ́, mú kí ife kíkorò yìí fò mí ru. Ṣugbọn ìfẹ́ tèmi kọ́, ìfẹ́ tìrẹ ni kí ó ṣẹ.” [ Angẹli kan yọ sí i láti ọ̀run láti ràn án lọ́wọ́. Pẹlu ọkàn wúwo, ó túbọ̀ gbadura gidigidi. Òógùn ojú rẹ̀ dàbí kí ẹ̀jẹ̀ máa kán bọ́ sílẹ̀.]
Ó bá dìde lórí adura, ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rí wọn tí wọn ń sùn nítorí àárẹ̀ ìbànújẹ́. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ̀ ń sùn ni! Ẹ dìde kí ẹ máa gbadura, kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò.”