LEFITIKU 4

4
Ẹbọ fún Ẹ̀ṣẹ̀ Tí Eniyan Bá Ṣèèṣì Dá
1OLUWA ní kí Mose 2sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, bí ẹnikẹ́ni bá ṣèèṣì ṣe ọ̀kankan ninu ohun tí OLUWA pa láṣẹ pé wọn kò gbọdọ̀ ṣe, ohun tí wọn óo ṣe nìyí:
3“Bí ó bá jẹ́ alufaa tí a fi àmì òróró yàn ni ó ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀, tí ó sì kó ẹ̀bi bá àwọn eniyan, kí ó fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ níwájú OLUWA, fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá. 4Yóo mú akọ mààlúù náà wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ níwájú OLUWA, yóo gbé ọwọ́ lé e lórí, yóo sì pa á níwájú OLUWA. 5Alufaa náà yóo wá gbà ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù náà, yóo gbé e wá sinu Àgọ́ Àjọ. 6Yóo ti ìka rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, yóo sì wọ́n ọn sílẹ̀ nígbà meje níwájú OLUWA, níwájú aṣọ ìkélé tí ó wà ní ibi mímọ́. 7Lára ẹ̀jẹ̀ tí ó kù, yóo fi sára àwọn ìwo pẹpẹ turari olóòórùn dídùn tí ó wà níwájú OLUWA, ninu Àgọ́ Àjọ. Yóo sì da ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù yòókù sílẹ̀ nídìí pẹpẹ ẹbọ sísun tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ náà. 8Yóo yọ́ gbogbo ọ̀rá akọ mààlúù tí ó fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ kúrò, ati gbogbo ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú rẹ̀; 9ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, pẹlu ọ̀rá tí ó bo ibi ìbàdí ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀ 10(gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń yọ wọ́n lára mààlúù tí wọn ń fi rú ẹbọ alaafia), yóo sì sun wọ́n níná lórí pẹpẹ ẹbọ sísun. 11Ṣugbọn awọ akọ mààlúù náà, ati gbogbo ẹran rẹ̀ ati orí rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀ ati nǹkan inú rẹ̀, ati ìgbẹ́ rẹ̀; 12pátá ni yóo gbé jáde kúrò ninu àgọ́, lọ síbìkan tí ó bá mọ́, níbi tí wọn ń da eérú sí, yóo sì kó igi jọ, yóo dáná sun ún níbẹ̀.
13“Tí ó bá jẹ́ pé gbogbo ìjọ eniyan Israẹli ni ó ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn tí ẹ̀ṣẹ̀ náà kò hàn sí ìjọ eniyan, tí wọ́n bá ṣe ọ̀kan ninu àwọn ohun gbogbo tí OLUWA ti pa láṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ ṣe, tí wọ́n sì jẹ̀bi, 14nígbà tí wọ́n bá mọ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá, tí wọ́n sì rí àṣìṣe wọn, gbogbo ìjọ eniyan náà yóo fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, wọn yóo fà á wá síbi Àgọ́ Àjọ. 15Àwọn àgbààgbà ninu àwọn eniyan náà yóo gbé ọwọ́ wọn lé orí akọ mààlúù yìí níwájú OLUWA, wọn óo sì pa á níbẹ̀. 16Lẹ́yìn náà ni alufaa tí a fi òróró yàn yóo mú ninu ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù yìí wá sinu Àgọ́ Àjọ. 17Yóo sì ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, yóo wọ́n ọn sílẹ̀ nígbà meje níwájú OLUWA, níwájú aṣọ ìbòjú tí ó wà níbi mímọ́. 18Yóo mú ninu ẹ̀jẹ̀ tí ó kù, yóo fi sára àwọn ìwo pẹpẹ tí ó wà níwájú OLUWA ninu Àgọ́ Àjọ, yóo sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sílẹ̀ ní ìdí pẹpẹ ẹbọ sísun tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. 19Yóo yọ gbogbo ọ̀rá rẹ̀ yóo sì sun ún lórí pẹpẹ. 20Bí ó ti ṣe akọ mààlúù tí wọ́n fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni yóo ṣe akọ mààlúù yìí pẹlu. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún wọn, OLUWA yóo sì dáríjì wọ́n. 21Lẹ́yìn náà, alufaa yóo gbé mààlúù yìí jáde kúrò ninu àgọ́, yóo sì sun ún bí ó ti sun mààlúù ti àkọ́kọ́; ó jẹ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo ìjọ eniyan náà.
22“Bí ìjòyè kan bá dẹ́ṣẹ̀, tí ó ṣèèṣì ṣe ọ̀kankan ninu àwọn ohun tí OLUWA Ọlọrun rẹ̀ pa láṣẹ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe, tí ó sì jẹ̀bi, 23nígbà tí wọ́n bá fi ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá yìí hàn án, yóo mú òbúkọ kan tí kò ní àbààwọ́n wá, yóo fi rúbọ. 24Yóo gbé ọwọ́ lé orí òbúkọ yìí, yóo sì pa á níbi tí wọ́n ti máa ń pa ẹran ẹbọ sísun níwájú OLUWA; ó jẹ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. 25Alufaa yóo ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹran tí wọ́n fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ yìí yóo fi sí ara àwọn ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun; yóo sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sílẹ̀ nídìí pẹpẹ. 26Yóo sun gbogbo ọ̀rá òbúkọ náà lórí pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rá ẹran tí wọ́n bá fi rú ẹbọ alaafia. Bẹ́ẹ̀ ni alufaa yóo ṣe ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, OLUWA yóo sì dáríjì í.
27“Bí ẹnìkan lásán ninu àwọn eniyan náà bá ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀, tí ó ṣe ọ̀kan ninu àwọn ohun tí OLUWA ti pa láṣẹ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe, tí ó sì jẹ̀bi, 28lẹ́yìn tí wọ́n bá fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó dá hàn án, yóo mú abo ewúrẹ́ tí kò ní àbààwọ́n wá, yóo fi rúbọ fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá. 29Yóo gbé ọwọ́ lé orí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ yìí, yóo sì pa á, níbi tí wọ́n ti ń rú ẹbọ sísun. 30Alufaa yóo sì ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, yóo fi sí ara ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, yóo sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sí ìdí pẹpẹ. 31Yóo yọ gbogbo ọ̀rá ewúrẹ́ náà, bí wọ́n ti ń yọ ọ̀rá ẹran tí wọ́n bá fi rú ẹbọ alaafia, alufaa yóo sì sun ún níná lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún un, OLUWA yóo sì dáríjì í.#Nọm 15:27-28
32“Bí ó bá jẹ́ pé, aguntan ni ó mú wá fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ó níláti jẹ́ abo aguntan tí kò ní àbààwọ́n. 33Kí ó gbé ọwọ́ lórí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ yìí, kí ó sì pa á fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń pa ẹran tí wọ́n bá fẹ́ fi rú ẹbọ sísun. 34Lẹ́yìn náà alufaa yóo yán ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ náà sí ara ìwo pẹpẹ ẹbọ sísun, yóo wá da ẹ̀jẹ̀ yòókù sídìí pẹpẹ. 35Yóo yọ́ gbogbo ọ̀rá rẹ̀, bí wọ́n ti ń yọ́ ọ̀rá ẹran tí wọ́n bá fi rú ẹbọ alaafia. Alufaa yóo kó o lé orí ẹbọ náà, yóo sì fi iná sun ún lórí pẹpẹ fún OLUWA. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá, OLUWA yóo sì dáríjì í.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

LEFITIKU 4: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀