Àwọn olódodo rí i, inú wọn dùn, àwọn aláìlẹ́bi fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà, wọ́n ń wí pé, ‘Dájúdájú, àwọn ọ̀tá wa ti parun, iná sì ti jó gbogbo ohun tí wọ́n fi sílẹ̀.’ “Nisinsinyii gba ti Ọlọrun, kí o sì wà ní alaafia; kí ó lè dára fún ọ. Gba ìtọ́ni rẹ̀, kí o sì kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ lékàn. Bí o bá yipada sí Olodumare, tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀, tí o bá mú ìwà aiṣododo kúrò ní ibùgbé rẹ, bí o bá ri wúrà mọ́ inú erùpẹ̀, tí o fi wúrà Ofiri sí ààrin àwọn òkúta ìsàlẹ̀ odò, bí Olodumare bá sì jẹ́ wúrà rẹ, ati fadaka olówó iyebíye rẹ, nígbà náà ni o óo láyọ̀ ninu Olodumare, o óo sì lè dúró níwájú Ọlọrun. Nígbà náà, o óo gbadura sí i, yóo sì gbọ́, o óo sì san ẹ̀jẹ́ rẹ. Ohunkohun tí o bá pinnu láti mú ṣe, yóo ṣeéṣe fún ọ, ìmọ́lẹ̀ yóo sì tàn sí ọ̀nà rẹ. Nítorí Ọlọrun a máa rẹ onigbeeraga sílẹ̀, a sì máa gba onírẹ̀lẹ̀. A máa gba àwọn aláìṣẹ̀, yóo sì gbà ọ́ là, nípa ìwà mímọ́ rẹ.”
Kà JOBU 22
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JOBU 22:19-30
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò