JOBU 14:1-6

JOBU 14:1-6 YCE

“Ẹnikẹ́ni tí obinrin bá bí, ọlọ́jọ́ kúkúrú ni, ó sì kún fún ìpọ́njú. Yóo kọ́ yọ bí òdòdó, lẹ́yìn náà yóo sì rẹ̀ dànù. Yóo kọjá lọ bí òjìji, kò sì ní sí mọ́. Ṣé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni o dojú kọ, tí ò ń bá ṣe ẹjọ́? Ta ló lè mú ohun mímọ́ jáde láti inú ohun tí kò mọ́? Kò sí ẹni náà. Níwọ̀n ìgbà tí a ti dá ọjọ́ fún un, tí o mọ iye oṣù rẹ̀, tí o sì ti pa ààlà tí kò lè rékọjá. Mú ojú rẹ kúrò lára rẹ̀, kí ó lè sinmi, kí ó sì lè gbádùn ọjọ́ ayé rẹ̀ bí alágbàṣe.