JOHANU 5:17-21

JOHANU 5:17-21 YCE

Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyìí, èmi náà sì ń ṣiṣẹ́.” Nítorí èyí àwọn Juu túbọ̀ ń wá ọ̀nà láti pa á, nítorí kì í ṣe pé ó ba Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́ nìkan ni, ṣugbọn ó pe Ọlọrun ní Baba rẹ̀, ó sọ ara rẹ̀ di ọ̀kan náà pẹlu Ọlọrun. Nígbà náà ni Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, Ọmọ kò lè dá nǹkankan ṣe yàtọ̀ sí ohun tí ó bá rí tí Baba ń ṣe. Àwọn ohun tí Ọmọ rí pé Baba ń ṣe ni òun náà ń ṣe. Nítorí Baba fẹ́ràn Ọmọ rẹ̀, ó sì fi ohun gbogbo tí ó ń ṣe hàn án. Yóo tún fi àwọn iṣẹ́ tí ó tóbi jù wọnyi lọ hàn án, kí ẹnu lè yà yín. Nítorí bí Baba ti ń jí àwọn òkú dìde, tí ó ń sọ wọ́n di alààyè, bẹ́ẹ̀ gan-an ni, ẹnikẹ́ni tí Ọmọ bá fẹ́ ni ó ń sọ di alààyè.

Àwọn fídíò fún JOHANU 5:17-21