JEREMAYA 46

46
Nebukadinesari ṣẹgun Ijipti ní Kakemiṣi
1Ọ̀rọ̀ tí OLUWA bá Jeremaya wolii sọ nípa àwọn orílẹ̀-èdè nìyí.
2Ọ̀rọ̀ lórí Ijipti: Nípa àwọn ọmọ ogun Farao Neko, ọba Ijipti, tí wọ́n wà létí odò Yufurate ní Kakemiṣi, àwọn tí Nebukadinesari, ọba Babiloni, ṣẹgun ní ọdún kẹrin tí Jehoiakimu ọmọ Josaya jọba Juda.
3“Ọ̀gágun Ijipti pàṣẹ fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pé,
‘Ẹ tọ́jú asà ati apata,
kí ẹ sì jáde sójú ogun!
4Ẹ̀yin ẹlẹ́ṣin, ẹ di ẹṣin yín ní gàárì, kí ẹ sì gùn wọ́n.
Ẹ dúró ní ipò yín, pẹlu àṣíborí lórí yín.
Ẹ pọ́n àwọn ọ̀kọ̀ yín,
kí ẹ gbé ihamọra irin yín wọ̀!’ ”
5Oluwa ní, “Kí ni mo rí yìí?
Ẹ̀rù ń bà wọ́n, wọ́n sì ń pada sẹ́yìn.
A ti lu àwọn ọmọ ogun wọn bolẹ̀,
wọ́n sì ń sálọ pẹlu ìkánjú;
wọn kò bojú wẹ̀yìn, ìpayà yí wọn ká!
6Àwọn tí ẹsẹ̀ wọn yá nílẹ̀ kò lè sálọ,#Ais 19:1-25; Isi 29:1–32:32
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ogun kò lè sá àsálà.
Ìhà àríwá, lẹ́bàá odò Yufurate, ni wọ́n tí fẹsẹ̀ kọ, tí wọ́n sì ṣubú.
7Ta ló ń ru bí odò Naili yìí,
bí odò tí ó kún bo bèbè rẹ̀?
8Ijipti ń ru bí odò Naili,
bí odò tí ó kún bo bèbè rẹ̀.
Ijipti wí pé, ‘N óo kún, n óo sì bo ayé mọ́lẹ̀,
n óo pa àwọn ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú wọn run.
9Ó yá, ẹṣin, ẹ gbéra,
kí kẹ̀kẹ́ ogun máa sáré kíkankíkan!
Kí àwọn ọmọ ogun máa nìṣó,
àwọn ọmọ ogun Etiopia ati Puti, tí wọ́n mọ asà á lò,
àwọn ọmọ ogun Ludi, tí wọ́n mọ ọfà á ta dáradára.’ ”
10Ọjọ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ọjọ́ náà,
ọjọ́ ẹ̀san, tí yóo gbẹ̀san ara rẹ̀ lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.
Idà rẹ̀ yóo pa àpatẹ́rùn, yóo sì mu ẹ̀jẹ̀ wọn ní àmuyó.
Nítorí OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní ń rúbọ,
ní ìhà àríwá, lẹ́bàá odò Yufurate.
11Gòkè lọ sí Gileadi, kí o lọ wá ìwọ̀ra, ẹ̀yin ará Ijipti,
asán ni gbogbo òògùn tí ẹ lò,
ẹ kò ní rí ìwòsàn.
12Àwọn orílẹ̀ èdè ti gbọ́ nípa ìtìjú yín,
igbe yín ti gba ayé kan;
nítorí àwọn ọmọ ogun ń rọ́ lu ara wọn;
gbogbo wọn sì ṣubú papọ̀.
Bíbọ̀ Nebukadinesari
13Ohun tí OLUWA sọ fún wolii Jeremaya nípa Nebukadinesari, ọba Babiloni nígbà tí ó ń bọ̀ wá ṣẹgun ilẹ̀ Ijipti nìyí:#Jer 43:10-13
14Ó ní, “Ẹ kéde ní Ijipti,
ẹ polongo ní Migidoli, ní Memfisi ati ní Tapanhesi.
Ẹ wí pé, ‘Ẹ gbáradì kí ẹ sì múra sílẹ̀,
nítorí ogun yóo run yín yíká.
15Kí ló dé tí àwọn akọni yín kò lè dúró?
Wọn kò lè dúró nítorí pé
OLUWA ni ó bì wọ́n ṣubú.’
16Ogunlọ́gọ̀ yín ti fẹsẹ̀ kọ, wọ́n sì ṣubú,
wọ́n wá ń wí fún ara wọn pé,
‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á pada sọ́dọ̀ àwọn eniyan wa,
ati sí ilẹ̀ tí wọn gbé bí wa,
nítorí ogun àwọn aninilára.’
17“Ẹ pa orúkọ Farao, ọba Ijipti dà,
ẹ pè é ní, ‘Aláriwo tí máa ń fi anfaani rẹ̀ ṣòfò.’
18Ọba, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun,
fi ara rẹ̀ búra pé, bí òkè Tabori ti rí láàrin àwọn òkè,
ati bí òkè Kamẹli létí òkun,
bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan tí yóo yọ si yín yóo rí.#46: 18 Ìtumọ̀ ẹsẹ yìí rúni lójú ní èdè Heberu.
19Ẹ di ẹrù yín láti lọ sí ìgbèkùn, ẹ̀yin ará Ijipti!
Nítorí pé Memfisi yóo di òkítì àlàpà,
yóo di ahoro, kò sì ní sí ẹni tí yóo máa gbé ibẹ̀.
20Ijipti dàbí ọmọ mààlúù tí ó lẹ́wà,
ṣugbọn irù kan, tí ó ti ìhà àríwá fò wá, ti bà lé e.
21Àwọn ọmọ ogun tí ó fi owó bẹ̀ lọ́wẹ̀,
dàbí akọ mààlúù àbọ́pa láàrin rẹ̀;
àwọn náà pẹ̀yìndà, wọ́n ti jọ sálọ,
wọn kò lè dúró;
nítorí ọjọ́ ìdààmú wọn ti dé bá wọn,
ọjọ́ ìjìyà wọn ti pé.
22Ó ń dún bí ejò tí ó ń sálọ;
nítorí pé àwọn ọ̀tá rẹ̀ ń bọ̀ tagbára tagbára,
wọ́n ń kó àáké bọ̀ wá bá a,
bí àwọn tí wọn ń gé igi.
23Wọn yóo gé igi inú igbó rẹ̀ lulẹ̀.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbó náà dí,
nítorí pé igi ibẹ̀ pọ̀ bí eṣú, tí wọn kò sì lóǹkà.
24A óo dójú ti àwọn ará Ijipti,
a óo fà wọ́n lé àwọn ará ìhà àríwá lọ́wọ́.
Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
25OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní: “N óo fi ìyà jẹ Amoni, oriṣa Tebesi, ati Farao, ati Ijipti pẹlu àwọn oriṣa rẹ̀, ati àwọn ọba rẹ̀. N óo fìyà jẹ Farao ati àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e. 26N óo fà wọ́n lé àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́; n óo fà wọ́n fún Nebukadinesari, ọba Babiloni, ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Lẹ́yìn náà, àwọn eniyan yóo máa gbé Ijipti bíi ti àtijọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
OLUWA Yóo Gba Àwọn Eniyan Rẹ̀ Là
27“Ṣugbọn ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi,
ọmọ Israẹli, ẹ má fòyà;
n óo gbà yín là láti ọ̀nà jíjìn,
n óo kó arọmọdọmọ yín yọ ní ilẹ̀ ìgbèkùn.
Ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, ẹ óo pada máa gbé ní ìrọ̀rùn.
Kò sì ní sí ẹni tí yóo dẹ́rù bà yín.
28Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi,#Jer 30:10-11
nítorí pé mo wà pẹlu yín.
N óo run gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí mo le yín lọ,
ṣugbọn n kò ní pa yín run.
Bí ó bá tọ́ kí n jẹ yín níyà, n óo jẹ yín níyà,
kìí ṣe pé n óo fi yín sílẹ̀ láìjẹ yín níyà.
Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JEREMAYA 46: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀