JEREMAYA 46:27

JEREMAYA 46:27 YCE

“Ṣugbọn ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi, ọmọ Israẹli, ẹ má fòyà; n óo gbà yín là láti ọ̀nà jíjìn, n óo kó arọmọdọmọ yín yọ ní ilẹ̀ ìgbèkùn. Ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, ẹ óo pada máa gbé ní ìrọ̀rùn. Kò sì ní sí ẹni tí yóo dẹ́rù bà yín.