JEREMAYA 35
35
Jeremaya ati Àwọn Ọmọ Rekabu
1OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ ní ìgbà ayé Jehoiakimu ọmọ Josaya, ọba Juda; ó ní, 2“Lọ sí ilé àwọn ọmọ Rekabu kí o bá wọn sọ̀rọ̀, mú wọn wá sinu ọ̀kan ninu àwọn yàrá tí ó wà ninu ilé OLUWA, kí o sì fi ọtí lọ̀ wọ́n.” 3Mo bá mú Jaasanaya ọmọ Jeremaya ọmọ Habasinaya ati àwọn arakunrin rẹ̀ ati gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ati gbogbo ìdílé Rekabu, 4mo mú wọn wá sinu ilé OLUWA. Mo kó wọn lọ sinu yàrá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Hanani, ọmọ Igidalaya eniyan Ọlọrun, yàrá náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ yàrá àwọn ìjòyè, lókè yàrá Maaseaya ọmọ Ṣalumu, aṣọ́nà. 5Mo gbé ìgò ọtí kalẹ̀ níwájú àwọn ọmọ Rekabu, mo kó ife tì í. Mo bá sọ fún wọn pé, “Ó yá, ẹ máa mu ọtí waini.”#2A. Ọba 23:36–24:6 2Kron 36:5-7
6Ṣugbọn wọ́n dáhùn pé, “A kò ní mu ọtí kankan nítorí pé Jonadabu, baba ńlá wa tíí ṣe ọmọ Rekabu ti pàṣẹ fún wa pé a kò gbọdọ̀ mu ọtí, ati àwa ati arọmọdọmọ wa títí lae. 7A kò gbọdọ̀ kọ́ ilé, a kò gbọdọ̀ dá oko, a kò gbọdọ̀ gbin ọgbà àjàrà. Ó ní inú àgọ́ ni kí á máa gbé ní gbogbo ọjọ́ ayé wa, kí ọjọ́ wa baà lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí à ń gbé. 8A gbọ́ràn sí Jonadabu baba ńlá wa lẹ́nu, à ń pa gbogbo àṣẹ tí ó pa fún wa mọ́, pé kí á má mu ọtí ní gbogbo ọjọ́ ayé wa, àwa, àwọn aya wa ati àwọn ọmọ wa lọkunrin ati lobinrin. 9Ó ní a kò gbọdọ̀ kọ́ ilé tí a óo máa gbé. A kò ṣe ọgbà àjàrà, tabi kí á dá oko, tabi kí á gbin ohun ọ̀gbìn. 10Inú àgọ́ ni à ń gbé, a sì pa gbogbo àṣẹ tí Jonadabu baba ńlá wa fún wa mọ́. 11Ṣugbọn nígbà tí Nebukadinesari, ọba Babiloni gbógun ti ilẹ̀ yìí, a wí fún ara wa pé kí á wá sí Jerusalẹmu nítorí ìbẹ̀rù àwọn ọmọ ogun, àwọn ará Kalidea ati ti àwọn ará Siria. Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe di ẹni tí ń gbé Jerusalẹmu.”
12OLUWA bá sọ fún Jeremaya pé, 13“Èmi OLUWA, àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní kí o lọ sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu pé, ṣé wọn kò ní gba ẹ̀kọ́ kí wọn sì fetí sí ọ̀rọ̀ mi ni? 14Àwọn ọmọ Rekabu pa òfin tí Jonadabu, baba ńlá wọn, fún wọn mọ́, pé kí wọn má mu ọtí waini, wọn kò sì mu ọtí rárá títí di òní olónìí, nítorí pé wọ́n pa àṣẹ baba ńlá wọn mọ́. Mo ti bá yín sọ̀rọ̀ ní ọpọlọpọ ìgbà, ṣugbọn ẹ kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. 15Mo ti rán gbogbo àwọn iranṣẹ mi, àwọn wolii, si yín, ní ọpọlọpọ ìgbà pé kí olukuluku yín yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú tí ó ń tọ̀, kí ẹ tún ìwà yín ṣe, kí ẹ má sá tẹ̀lé àwọn oriṣa kiri, kí ẹ yé máa sìn wọ́n; kí ẹ lè máa gbé ilẹ̀ tí mo fún ẹ̀yin ati àwọn baba ńlá yín. Ṣugbọn ẹ kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi, ẹ kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. 16Àwọn ọmọ Jonadabu, ọmọ Rekabu mú àṣẹ baba ńlá wọn tí ó pa fún wọn ṣẹ, ṣugbọn àwọn eniyan wọnyi kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. 17Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, ni mo sọ pé n óo jẹ́ kí ibi bá àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu, nítorí pé mo bá wọn sọ̀rọ̀, wọn kò gbọ́; mo pè wọ́n, wọn kò dáhùn.”
18Ṣugbọn Jeremaya sọ fún àwọn ọmọ Rekabu pé, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Nítorí pé ẹ gbọ́ràn sí Jonadabu baba ńlá yín lẹ́nu, ẹ sì pa gbogbo òfin rẹ̀ mọ́, ẹ sì ń ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ pé kí ẹ máa ṣe, 19nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní títí lae, kò ní sí ìgbà kan tí Jonadabu, ọmọ Rekabu kò ní ní ẹnìkan tí yóo máa ṣe iṣẹ́ ìsìn níwájú mi.’ ”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JEREMAYA 35: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: