JEREMAYA 25
25
Àwọn Ọ̀tá láti Ìhà Àríwá
1Ní ọdún kẹrin tí Jehoiakimu, ọmọ Josaya jọba ní Juda, tí ó jẹ́ ọdún kinni tí Nebukadinesari jọba Babiloni, Jeremaya wolii gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA nípa gbogbo àwọn ará Juda. 2Jeremaya sọ ọ̀rọ̀ náà fún gbogbo àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu. 3Ó ní, “Fún ọdún mẹtalelogun, láti ọdún kẹtala tí Josaya ọmọ Amoni ti jọba Juda, títí di ọjọ́ òní, ni OLUWA ti ń bá mi sọ̀rọ̀, tí mo sì ti ń sọ ọ́ fun yín lemọ́lemọ́, ṣugbọn tí ẹ kò sì gbọ́. 4Ẹ kò fetí sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà gbogbo ni OLUWA ń rán àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀, si yín, tí wọn ń sọ fun yín pé 5kí olukuluku yín yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú rẹ̀ ati iṣẹ́ ibi tí ó ń ṣe, kí ẹ lè máa gbé ilẹ̀ tí OLUWA fún ẹ̀yin ati àwọn baba ńlá yín títí lae, láti ìgbà àtijọ́. 6Wọ́n ní kí ẹ má wá àwọn oriṣa lọ, kí ẹ má bọ wọ́n, kí ẹ má sì sìn wọ́n. Wọ́n ní kí ẹ má fi iṣẹ́ ọwọ́ yín mú un bínú, kí ó má baà ṣe yín ní ibi.” 7OLUWA alára ní, “Mo wí, ṣugbọn ẹ kò gbọ́ tèmi; kí ẹ lè fi iṣẹ́ ọwọ́ yín mú mi bínú, fún ìpalára ara yín.”#2A. Ọba 24:12-16; 2 Kọr 36:5-7; Dan 1:1-2
8Ó ní, “Nítorí pé ẹ kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, 9n óo ranṣẹ lọ kó gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àríwá wá. N óo ranṣẹ sí Nebukadinesari ọba Babiloni, iranṣẹ mi, n óo jẹ́ kí wọn wá dó ti ilẹ̀ yìí, ati àwọn tí ń gbé ibẹ̀. Gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó wà ní agbègbè ilẹ̀ yìí ni n óo parun patapata, tí n óo sọ di àríbẹ̀rù, ati àrípòṣé, ati ohun ẹ̀gàn títí lae. 10N óo pa ìró ayọ̀ ati ẹ̀rín rẹ́ láàrin wọn, ẹnìkan kò sì ní gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ohùn iyawo tuntun mọ́. A kò ní gbọ́ ìró ọlọ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí iná fìtílà mọ́. 11Gbogbo ilẹ̀ yìí yóo di àlàpà ati aṣálẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi yóo sì sin ọba Babiloni fún aadọrin ọdún. 12Nígbà tí aadọrin ọdún bá pé, n óo jẹ ọba Babiloni ati orílẹ̀-èdè rẹ̀, ati ilẹ̀ àwọn ará Kalidea níyà, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. N óo sì sọ ibẹ̀ di àlàpà títí ayé. 13N óo mú gbogbo ọ̀rọ̀ burúkú tí mo ti sọ nípa ilẹ̀ náà ṣẹ, ati gbogbo ohun tí a kọ sinu ìwé yìí, àní àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jeremaya sọ nípa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè. 14Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati àwọn ọba alágbára yóo sọ àwọn ará Babiloni pàápàá di ẹrú, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san ìṣe wọn ati iṣẹ́ ọwọ́ wọn.”#a Jer 7:34; 16:9 b Ifi 18:22-23
Ìdájọ́ OLUWA lórí Àwọn Orílẹ̀-èdè náà#2Kron 36:21; Jer 29:10; Dan 9:2
15OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ fún mi pé, “Gba ife ọtí ibinu yìí lọ́wọ́ mi, kí o fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí n óo rán ọ sí mu. 16Wọn yóo mu ún, wọn yóo sì máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n, wọn yóo máa ṣe bí aṣiwèrè nítorí ogun tí n óo rán sí ààrin wọn.”
17Mo bá gba ife náà lọ́wọ́ OLUWA, mo sì fún gbogbo orílẹ̀-èdè tí OLUWA rán mi sí mu: 18Jerusalẹmu ati àwọn ìlú Juda, àwọn ọba ilẹ̀ Juda ati àwọn ìjòyè wọn, kí wọn lè di ahoro ati òkítì àlàpà, nǹkan àrípòṣé ati ohun tí à ń fi í ṣépè, bí ó ti rí ní òní yìí.
19N óo fún Farao, ọba Ijipti mu, ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ 20ati àwọn àlejò tí wọ́n wà láàrin wọn. N óo fún gbogbo àwọn ọba Usi mu, ati gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Filistini, (Aṣikeloni, Gasa, Ekironi ati àwọn tí wọ́n kù ní Aṣidodu). 21N óo fún Edomu mu, ati Moabu, ati àwọn ọmọ Amoni; 22ati gbogbo àwọn ọba Tire, ati àwọn ọba Sidoni, ati gbogbo àwọn ọba erékùṣù tí ó wà ní òdìkejì òkun. 23N óo fún Dedani mu, ati Tema, ati Busi ati gbogbo àwọn tí wọn ń gé ẹsẹ̀ irun wọn. 24N óo fún gbogbo àwọn ọba Arabia mu ati gbogbo àwọn ọba oríṣìíríṣìí ẹ̀yà tí wọn ń gbé aṣálẹ̀. 25N óo fún gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Simiri mu, ati gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Elamu ati gbogbo àwọn ti ilẹ̀ Media; 26ati gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ àríwá, ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí, ati àwọn tí wọ́n wà lọ́nà jíjìn. N óo sì fún àwọn ìjọba gbogbo ilẹ̀ ayé mu pẹlu. Lẹ́yìn tí gbogbo wọn bá ti mu tiwọn tán, ọba Babiloni yóo wá mu tirẹ̀.
27OLUWA ní kí n sọ fún wọn pé, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní kí ẹ mu ọtí kí ẹ yó, kí ẹ sì máa bì, ẹ ṣubú lulẹ̀ kí ẹ má dìde mọ́; nítorí ogun tí n óo jẹ́ kí ó bẹ́ sílẹ̀ ní ààrin yín. 28Bí wọn bá kọ̀ tí wọn kò gba ife náà lọ́wọ́ rẹ kí wọ́n sì mu ún, wí fún wọn pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní wọ́n gbọdọ̀ mu ún ni! 29Nítorí pé mo ti bẹ̀rẹ̀ sí mú kí ibi ṣẹlẹ̀ sórí ìlú tí à ń fi orúkọ mi pè yìí, ǹjẹ́ ẹ lè lọ láìjìyà bí? Rárá o, ẹ kò ní lọ láìjìyà nítorí pé mo ti pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn tí wọn ń gbé orí ilẹ̀ ayé kú ikú idà, èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
30“Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí fún wọn pé:
‘OLUWA yóo bú ramúramù láti òkè,
yóo pariwo láti ibi mímọ́ rẹ̀.
Yóo bú ramúramù mọ́ àwọn eniyan inú agbo rẹ̀.
Yóo kígbe mọ́ gbogbo aráyé bí igbe àwọn tí ń tẹ àjàrà.
31Ariwo náà yóo kàn dé òpin ayé,
nítorí pé OLUWA ní ẹjọ́ láti bá àwọn orílẹ̀-èdè rò.
Yóo dá gbogbo eniyan lẹ́jọ́,
yóo fi idà pa àwọn eniyan burúkú,
OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.’ ”
32OLUWA àwọn ọmọ ogun ní ibi yóo máa ṣẹlẹ̀ láti orílẹ̀-èdè kan dé ekeji, ìjì ńlá yóo sì jà láti òpin ayé wá. 33Òkú àwọn tí OLUWA yóo pa ní ọjọ́ náà yóo kún inú ayé láti òpin kan dé ekeji. Ẹnikẹ́ni kò ní ṣọ̀fọ̀ wọn, kò sí ẹni tí yóo gbé òkú wọn nílẹ̀; wọn kò ní sin wọ́n. Wọn yóo dàbí ìgbẹ́ lórí ilẹ̀.
34Ẹ̀yin olùṣọ́-aguntan, ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ kígbe. Ẹ̀yin oluwa àwọn agbo ẹran, ẹ máa yíra mọ́lẹ̀ ninu eérú nítorí àkókò tí a óo pa yín, tí a óo sì tu yín ká ti tó, ẹ óo sì ṣubú lulẹ̀ bí ẹran àbọ́pa. 35Kò ní sí ààbò mọ́ fún àwọn olùṣọ́-aguntan, kò ní sí ọ̀nà ati sá àsálà fún àwọn oluwa àwọn agbo ẹran.
36Ẹ gbọ́ igbe àwọn olùṣọ́-aguntan
ati ẹkún ẹ̀dùn ti àwọn oluwa agbo ẹran;
nítorí OLUWA ń ba ibùjẹ ẹran wọn jẹ́.
37Pápá oko tútù tí ìbẹ̀rù kò sí níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ ti di ahoro
nítorí ibinu gbígbóná OLUWA.
38Bíi kinniun tí ó fi ihò rẹ̀ sílẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni OLUWA fi àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀,
ilẹ̀ wọn sì ti di ahoro
nítorí idà apanirun ati ibinu gbígbóná OLUWA.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
JEREMAYA 25: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: