JEREMAYA 23

23
Ìrètí Ọjọ́ Iwájú
1OLUWA ní, “Àwọn olùṣọ́-aguntan tí wọn ń tú àwọn agbo aguntan mi ká, tí wọn ń run wọ́n gbé!” 2Nítorí náà, OLUWA, Ọlọrun Israẹli sọ nípa àwọn tí ó fi ṣọ́ àwọn eniyan rẹ̀, láti máa bojútó wọn pé, “Ẹ ti tú àwọn aguntan mi ká, ẹ ti lé wọn dànù, ẹ kò sì tọ́jú wọn. N óo wá ṣe ìdájọ́ fun yín nítorí iṣẹ́ ibi yín, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. 3N óo kó àwọn tí wọ́n kù ninu àwọn aguntan mi jọ láti gbogbo ibi tí mo lé wọn lọ. N óo kó wọn pada sinu agbo wọn. Wọn óo bímọ lémọ, wọn óo sì máa pọ̀ sí i. 4N óo wá fún wọn ní olùṣọ́ mìíràn tí yóo tọ́jú wọn. Ẹ̀rù kò ní bà wọ́n mọ́, wọn kò ní fòyà, ọ̀kankan ninu wọn kò sì ní sọnù, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
5“Wò ó! Àkókò kan ń bọ̀, tí n óo gbé Ẹ̀ka olódodo kan dìde ninu ìdílé Dafidi. Yóo jọba, yóo hùwà ọlọ́gbọ́n, yóo sì ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo ní ilẹ̀ náà. 6Juda yóo rí ìgbàlà ní ìgbà tirẹ̀, Israẹli yóo sì wà láìléwu. Orúkọ tí a óo máa pè é ni ‘OLUWA ni òdodo wa.’#Jer 33:14-16
7“Nítorí náà àkókò kan ń bọ̀, tí wọn kò ní máa búra ní orúkọ OLUWA tí ó kó àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti mọ́, 8ṣugbọn tí wọn yóo máa wí pé, ‘Ní orúkọ OLUWA tí ó kó àwọn ọmọ ilé Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ àríwá, ati gbogbo ilẹ̀ tí wọn kó wọn lẹ́rú lọ, tí ó sì mú wọn pada sí ilẹ̀ wọn.’ Wọn óo wá máa gbé orí ilẹ̀ wọn nígbà náà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Iṣẹ́ tí Jeremaya Jẹ́ nípa Àwọn Wolii
9Ọkàn mi bàjẹ́ nítorí àwọn wolii,
gbogbo ara mi ń gbọ̀n.
Mo dàbí ọ̀mùtí tí ó ti mu ọtí yó,
mo dàbí ẹni tí ọtí ń pa,
nítorí OLUWA, ati nítorí ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀.
10Nítorí pé ilẹ̀ náà kún fún àgbèrè ẹ̀sìn,
ọ̀nà ibi ni wọ́n ń tọ̀,
wọn kò sì lo agbára wọn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́
nítorí ègún, ilẹ̀ ti di gbígbẹ
gbogbo pápá oko ló ti gbẹ.
11Ati wolii, ati alufaa, ìwà burúkú ni wọ́n ń hù,
ní ilé mi pàápàá mo rí iṣẹ́ ibi wọn,
èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
12Nítorí náà ọ̀nà wọn yóo dàbí ọ̀nà tí ń yọ̀ ninu òkùnkùn,
a óo tì wọ́n sinu rẹ̀, wọn yóo sì ṣubú,
nítorí n óo mú kí ibi bá wọn ní ọdún ìjìyà wọn.
13Mo rí nǹkankan tí ó burú lọ́wọ́ àwọn wolii Samaria:
Ẹ̀mí oriṣa Baali ni wọ́n fi ń sọ àsọtẹ́lẹ̀;
wọ́n sì ń ṣi àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi, lọ́nà.
14Mo rí nǹkankan tí ó bani lẹ́rù lọ́wọ́ àwọn wolii Jerusalẹmu:#Jẹn 18:20; Isi 16:49
Wọ́n ń ṣe àgbèrè ẹ̀sìn,
wọ́n ń hùwà èké;
wọ́n ń ran àwọn ẹni ibi lọ́wọ́,
kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni yipada kúrò ninu iṣẹ́ ibi rẹ̀.
Gbogbo wọn ti di ará Sodomu lójú mi,
àwọn ará Jerusalẹmu sì dàbí àwọn ará Gomora.
15Nítorí náà OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ nípa àwọn wolii pé:
N óo fún wọn ní ewé igi kíkorò jẹ,
n óo fún wọn ní omi májèlé mu.
Nítorí pé láti ọ̀dọ̀ àwọn wolii Jerusalẹmu
ni ìwà burúkú ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ yìí.
16OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yín, tí wọ́n ń mu yín gbẹ́kẹ̀lé irọ́. Ohun tí wọn fẹ́ lọ́kàn wọn ni wọ́n ń sọ, kì í ṣe ẹnu èmi OLUWA ni wọ́n ti gbọ́ ọ. 17Wọ́n ń sọ lemọ́lemọ́ fún àwọn tí wọn kò ka ọ̀rọ̀ OLUWA sí pé, yóo dára fún wọn. Wọ́n ń wí fún gbogbo àwọn tí wọn ń tẹ̀lé àìgbọràn ọkàn wọn pé ibi kò ní bá wọn.”
18Mo ní, “Èwo ninu wọn ló wà ninu ìgbìmọ̀ OLUWA tí ó ti ṣe akiyesi tí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀? Èwo ninu wọn ni ó fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó sì gbà á gbọ́? 19Ẹ wo ibinu OLUWA bí ó ṣe ń jà bí ìjì! Ó ti fa ibinu yọ. Ó sì ń jà bí ìjì líle. Yóo tú dà sí orí àwọn eniyan burúkú. 20Inú OLUWA kò ní rọ̀ títí yóo fi ṣe ohun tí ó pinnu lọ́kàn rẹ̀. Yóo ye wọn nígbà tí ọjọ́ ìkẹyìn bá dé.”
21OLUWA ní, “N kò rán àwọn wolii níṣẹ́, sibẹsibẹ aré ni wọ́n ń sá lọ jíṣẹ́. N kò bá wọn sọ̀rọ̀, sibẹsibẹ wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀. 22Bí wọn bá ti bá mi pé ní ìgbìmọ̀ ni, wọn ìbá kéde ọ̀rọ̀ mi fún àwọn eniyan mi, wọn ìbá yí wọn pada kúrò lọ́nà ibi tí wọn ń rìn, ati iṣẹ́ ibi tí wọn ń ṣe.
23“Ṣé nítòsí nìkan ni mo ti jẹ́ Ọlọrun ni, èmi kì í ṣe Ọlọrun ọ̀nà jíjìn? 24Ǹjẹ́ ẹnìkan lè sápamọ́ sí ìkọ̀kọ̀ kan tí n kò fi ní rí i? Kì í ṣe èmi ni mo wà ní gbogbo ọ̀run tí mo sì tún wà ní gbogbo ayé?#Ọgb 1:7; Sir 16:17 25Mo gbọ́ ohun tí àwọn wolii tí wọn ń fi orúkọ mi sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ń sọ, tí wọn ń sọ pé, àwọn lá àlá, àwọn lá àlá! 26Irọ́ yóo ti pẹ́ tó lọ́kàn àwọn wolii èké tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn. 27Wọ́n ṣebí àwọn lè fi àlá tí olukuluku wọn ń rọ́ fún ẹnìkejì rẹ̀ mú àwọn eniyan mi gbàgbé orúkọ mi, bí àwọn baba wọn ṣe gbàgbé mi, tí wọn ń tẹ̀lé oriṣa Baali. 28Kí àwọn wolii tí wọn lá àlá máa rọ́ àlá wọn, ṣugbọn ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí ó sọ ọ́ pẹlu òtítọ́. Báwo ni a ṣe lè fi ìyàngbò wé ọkà? 29Ṣebí bí iná ni ọ̀rọ̀ mi rí, ati bí òòlù irin tíí fọ́ àpáta sí wẹ́wẹ́? 30Nítorí náà, mo dojú ìjà kọ àwọn wolii tí wọn ń sọ ọ̀rọ̀ tí wọn gbọ́ lẹ́nu ara wọn, tí wọn ń sọ pé èmi ni mo sọ ọ́. 31Mo lòdì sí àwọn wolii tí wọn ń sọ ọ̀rọ̀ ti ara wọn, tí wọn ń sọ pé èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. 32Mo lòdì sí àwọn wolii tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ àlá irọ́, tí wọn ń rọ́ àlá irọ́ wọn, tí wọn fí ń ṣi àwọn eniyan mi lọ́nà pẹlu irọ́ ati ìṣekúṣe wọn, nígbà tí n kò rán wọn níṣẹ́, tí n kò sì fún wọn láṣẹ. Nítorí náà wọn kò ṣe àwọn eniyan wọnyi ní anfaani kankan. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Ẹrù OLUWA
33Bí ọ̀kan ninu àwọn eniyan wọnyi, tabi wolii kan, tabi alufaa kan, bá bi ọ́ léèrè pé, “Kí ni iṣẹ́ tí OLUWA rán?” Wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin gan-an ni ẹ jẹ́ ẹrù.#23:33 Ọ̀rọ̀ kan náà ni Heberu ń lò fún “iṣẹ́” ati “ẹrù.” OLUWA sì ní òun óo gbé yín sọnù.” 34Bí wolii kan tabi alufaa kan tabi ẹnikẹ́ni ninu àwọn eniyan wọnyi bá wí pé òun ń jẹ́ iṣẹ́ OLUWA, n óo jẹ olúwarẹ̀ ati ilé rẹ̀ níyà. 35Báyìí ni kí ẹnìkọ̀ọ̀kan máa wí fún ẹnìkejì rẹ, ati fún arakunrin rẹ̀, “Kí ni ìdáhùn OLUWA?” tabi “Kí ni OLUWA wí?” 36Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ mẹ́nuba ẹrù OLUWA mọ́. Nítorí pé èrò ọkàn olukuluku ni ẹrù OLUWA lójú ara rẹ̀; ẹ sì ń yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun alààyè po, ọ̀rọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun wa. 37Bí ẹ óo ti máa bèèrè lọ́wọ́ àwọn wolii ni pé, “Kí ni ìdáhùn tí OLUWA fún ọ?” Tabi, “Kí ni OLUWA wí?” 38Ṣugbọn bí ẹ bá mẹ́nu ba “Ẹrù OLUWA,” lẹ́yìn tí mo ti ranṣẹ si yín pé ẹ kò gbọdọ̀ mẹ́nu bà á mọ́, 39tìtorí rẹ̀, n óo sọ yín sókè,#23:39 Ọ̀rọ̀ tí Heberu lò fún “gbé sókè” ati “iṣẹ́” ati “ẹrù” fi ara pẹ́ ara wọn. n óo sì gbe yín sọnù kúrò níwájú mi, àtẹ̀yin, àtìlú tí mo fi fún ẹ̀yin, ati àwọn baba ńlá yín. 40N óo mú ẹ̀gàn ati ẹ̀sín ba yín, tí ẹ kò ní gbàgbé títí ayérayé.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JEREMAYA 23: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀