JEREMAYA 22:15-16

JEREMAYA 22:15-16 YCE

Ṣé ilé kedari tí o kọ́ ni ó sọ ọ́ di ọba? Wo baba rẹ, ṣé kò rí jẹ ni, tabi kò rí mu? Ṣebí ó ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo, ṣebí ó sì dára fún un. Ẹjọ́ ẹ̀tọ́ níí dá fún talaka ati aláìní, ohun gbogbo sì ń lọ dáradára. Ṣebí èyí ni à ń pè ní kí eniyan mọ OLUWA? OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.