JAKỌBU 1:5-8
JAKỌBU 1:5-8 YCE
Bí ẹnikẹ́ni bá wà ninu yín, tí ọgbọ́n kù díẹ̀ kí ó tó fún, kí olúwarẹ̀ bèèrè lọ́dọ̀ Ọlọrun, yóo sì fún un. Nítorí Ọlọrun lawọ́, kì í sìí sìrègún. Ṣugbọn olúwarẹ̀ níláti bèèrè pẹlu igbagbọ, láì ṣiyèméjì. Nítorí ẹni tí ó bá ń ṣiyèméjì dàbí ìgbì omi òkun, tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri tí ó sì ń rú sókè. Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ má ṣe rò pé òun óo rí nǹkankan gbà lọ́dọ̀ Oluwa: ọkàn rẹ̀ kò papọ̀ sí ọ̀nà kan, ó ń ṣe ségesège, ó ń ṣe iyè meji.







