Ṣugbọn ohun tí ó sọ fún Ọmọ náà ni pé, “Ìfẹ́ rẹ wà títí laelae, Ọlọrun, ọ̀pá òtítọ́ ni ọ̀pá ìjọba rẹ. O fẹ́ràn òdodo, o kórìíra ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí èyí, Ọlọrun, àní Ọlọrun rẹ, fi òróró yàn ọ́ láti gbé ọ ga ju àwọn ẹgbẹ́ rẹ lọ.” Ó tún sọ pé, “O ti wà láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, Oluwa, ìwọ ni o fi ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀. Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni àwọn ọ̀run. Wọn óo parẹ́ ṣugbọn ìwọ óo wà títí. Gbogbo wọn óo gbó bí aṣọ. Gẹ́gẹ́ bí eniyan tií ká aṣọ ni ìwọ óo ká wọn. Gẹ́gẹ́ bí aṣọ, a óo pààrọ̀ wọn. Ṣugbọn ní tìrẹ, bákan náà ni o wà. Kò sí òpin sí iye ọdún rẹ.” Èwo ninu àwọn angẹli ni ó fi ìgbà kan sọ fún pé, “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí n óo fi ṣe àwọn ọ̀tá rẹ ní àpótí ìtìsẹ̀ rẹ?” Ṣebí ẹ̀mí tí ó jẹ́ iranṣẹ ni gbogbo àwọn angẹli. A rán wọn láti ṣiṣẹ́ nítorí àwọn tí yóo jogún ìgbàlà.
Kà HEBERU 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: HEBERU 1:8-14
7 Awọn ọjọ
Bíbélì jẹ iwe èto itan bi Ọlọrun ṣe fi ara rẹ hàn fún ẹdá ènìyàn. Ojẹ àlàyé bi Ọlọrun to fẹran iṣẹda rẹ, pẹlú ipò ìṣubú wọn, síbẹ o nọwọ rẹ lati fi kanwo, lati gb'awọn lá, wo wọn sàn ati tuwọn ni ide Kúrò lọwọ ikú ati iparun ayérayé. Èrò idi fún ẹkọ yi ni lati ran wa lọwọ ki ale mọ̀ Ọlọrun baba lati inu Kristi Ọmọ.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò