JẸNẸSISI 6:12-14

JẸNẸSISI 6:12-14 YCE

Ọlọrun rí i pé ayé ti bàjẹ́, nítorí pé ìwà ìbàjẹ́ ni gbogbo eniyan ń hù. Ọlọrun bá sọ fún Noa pé, “Mo ti pinnu láti pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run, nítorí ìwà ipá wọn ti gba gbogbo ayé, àtàwọn àtayé ni n óo parun. Nítorí náà, fi igi goferi kan ọkọ̀ ojú omi fún ara rẹ. Ṣe ọpọlọpọ yàrá sinu rẹ̀, kí o sì fi ọ̀dà kùn ún ninu ati lóde.