JẸNẸSISI 3:7-19

JẸNẸSISI 3:7-19 YCE

Ojú àwọn mejeeji bá là, wọ́n sì mọ̀ pé ìhòòhò ni àwọn wà, wọ́n bá gán ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sán an mọ́ ìdí. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbúròó OLUWA Ọlọrun tí ń rìn ninu ọgbà. Wọ́n bá sá pamọ́ sí ààrin àwọn igi ọgbà. Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun pe ọkunrin náà, ó bi í pé, “Níbo ni o wà?” Ó dá Ọlọrun lóhùn, ó ní, “Nígbà tí mo gbúròó rẹ ninu ọgbà, ẹ̀rù bà mí, mo bá farapamọ́ nítorí pé ìhòòhò ni mo wà.” Ọlọrun bi í pé, “Ta ló sọ fún ọ pé ìhòòhò ni o wà? Àbí o ti jẹ ninu èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé o kò gbọdọ̀ jẹ?” Ọkunrin náà dáhùn, ó ní, “Obinrin tí o fi tì mí ni ó fún mi ninu èso igi náà, mo sì jẹ ẹ́.” OLUWA Ọlọrun bi obinrin náà pé, “Irú kí ni o dánwò yìí?” Obinrin náà dáhùn, ó ní, “Ejò ni ó tàn mí tí mo fi jẹ ẹ́.” OLUWA Ọlọrun bá sọ fún ejò náà pé, “Nítorí ohun tí o ṣe yìí, o di ẹni ìfibú jùlọ láàrin gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn ati àwọn ẹranko. Àyà rẹ ni o óo máa fi wọ́ káàkiri, erùpẹ̀ ni o óo sì máa jẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. N óo dá ọ̀tá sí ààrin ìwọ ati obinrin náà, ati sí ààrin atọmọdọmọ rẹ ati atọmọdọmọ rẹ̀. Wọn óo máa fọ́ ọ lórí, ìwọ náà óo sì máa bù wọ́n ní gìgísẹ̀ jẹ.” Lẹ́yìn náà Ọlọrun wí fún obinrin náà pé, “N óo fi kún ìnira rẹ nígbà tí o bá lóyún, ninu ìrora ni o óo máa bímọ. Sibẹsibẹ, lọ́dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóo máa fà sí, òun ni yóo sì máa ṣe olórí rẹ.” Ó sọ fún Adamu, pé, “Nítorí pé o gba ohun tí aya rẹ wí fún ọ, o sì jẹ ninu èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé o kò gbọdọ̀ jẹ, mo fi ilẹ̀ gégùn-ún títí lae nítorí rẹ. Pẹlu ìnira ni o óo máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Ẹ̀gún ati òṣùṣú ni ilẹ̀ yóo máa hù jáde fún ọ, ewéko ni o óo sì máa jẹ. Iṣẹ́ àṣelàágùn ni o óo máa ṣe, kí o tó rí oúnjẹ jẹ, títí tí o óo fi pada sí ilẹ̀, nítorí inú rẹ̀ ni a ti mú ọ wá. Erùpẹ̀ ni ọ́, o óo sì pada di erùpẹ̀.”

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú JẸNẸSISI 3:7-19