ISIKIẸLI 8
8
Ìran Keji tí Ọlọrun Fi Han Isikiẹli
(8:1–10:22)
Ìwà Ìbọ̀rìṣà Ní Jerusalẹmu
1Ní ọjọ́ karun-un, oṣù kẹfa ọdún kẹfa tí a ti wà ní ìgbèkùn, bí mo ti jókòó ninu ilé mi, tí àwọn àgbààgbà Juda sì jókòó níwájú mi, agbára OLUWA Ọlọrun bà lé mi níbẹ̀. 2Nígbà tí mo wò, mo rí nǹkankan tí ó dàbí eniyan. Láti ibi tí ó dàbí ìbàdí rẹ̀ dé ilẹ̀ jẹ́ iná, ibi ìbàdí rẹ̀ sókè ń kọ mànàmànà bí idẹ dídán. 3Ó na nǹkankan tí ó dàbí ọwọ́, ó fi gbá ìdí irun orí mi mú, ẹ̀mí sì gbé mi sókè sí agbede meji ọ̀run ati ayé, ó gbé mi lọ sí Jerusalẹmu, ninu ìran Ọlọrun, ó gbé mi sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá gbọ̀ngàn ti inú tí ó kọjú sí ìhà àríwá, níbi tí wọ́n gbé ère tí ń múni jowú sí.#Isi 1:27
4Mo rí ìfarahàn ògo Ọlọrun Israẹli níbẹ̀ bí mo ti rí i lákọ̀ọ́kọ́ ní àfonífojì. 5Ó bá sọ fún mi, pé: “Ọmọ eniyan, gbójú sókè sí apá àríwá.” Mo bá gbójú sókè sí apá àríwá. Wò ó! Mo rí ère kan tí ń múni jowú ní ìhà àríwá ẹnu ọ̀nà pẹpẹ ìrúbọ.#Isi 1:28
6OLUWA sọ fún mi pé: “Ọmọ eniyan, ṣé o rí ohun tí wọn ń ṣe? Ṣé o rí nǹkan ìríra ńlá tí àwọn ọmọ Israẹli ń ṣe níhìn-ín láti lé mi jìnnà sí ilé mímọ́ mi? N óo fi nǹkan ìríra ńlá mìíràn hàn ọ́.”
7OLUWA bá tún gbé mi lọ sí ẹnu ọ̀nà gbọ̀ngàn, nígbà tí mo wò yíká, mo rí ihò kan lára ògiri. 8Ó bá sọ fún mi pé, “Ọmọ eniyan, gbẹ́ ara ògiri yìí.” Nígbà tí mo gbẹ́ ara ògiri náà, mo rí ìlẹ̀kùn kan! 9Ó bá sọ fún mi pé, “Wọlé kí o rí nǹkan ìríra tí wọn ń ṣe níbẹ̀.” 10Mo bá wọlé láti wo ohun tí ó wà níbẹ̀. Mo rí àwòrán oríṣìíríṣìí kòkòrò ati ti ẹranko, tí ń rí ni lára, ati gbogbo oriṣa àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n yà sí ara ògiri yíká. 11Mo sì rí aadọrin ninu àwọn àgbààgbà àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n dúró níwájú àwọn oriṣa wọnyi, Jaasanaya ọmọ Ṣafani dúró láàrin wọn. Olukuluku mú ohun tí ó fi ń sun turari lọ́wọ́, èéfín turari sì ń fẹ́ lọ sókè. 12OLUWA tún bi mí pé: “Ọmọ eniyan, ṣé o rí ohun tí àwọn àgbààgbà ilé Israẹli ń ṣe ninu òkùnkùn? Ṣé o rí ohun tí olukuluku ń ṣe ninu yàrá tí ó kún fún àwòrán ère oriṣa? Wọ́n ń wí pé, ‘OLUWA kò rí wa, ó ti kọ ilẹ̀ wa sílẹ̀.’ ”
13Ó tún sọ fún mi pé, “N óo fi nǹkan ìríra ńlá mìíràn tí ó jù báyìí lọ tí wọn ń ṣe hàn ọ́.” 14Nígbà náà ni ó mú mi lọ sí ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní ìhà àríwá ilé OLUWA. Wò ó, mo rí àwọn obinrin kan níbẹ̀, tí wọ́n jókòó, tí wọn ń sunkún nítorí Tamusi.
15Ó sì bi mí pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, ǹjẹ́ o rí ohun tí wọn ń ṣe yìí? O óo tún rí nǹkan ìríra tí ó ju èyí lọ.” 16Ó mú mi wọ inú gbọ̀ngàn tí ó wà ninu ilé OLUWA; mo bá rí àwọn ọkunrin mẹẹdọgbọn kan, wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà tẹmpili ilé OLUWA, láàrin ìloro ati pẹpẹ. Wọ́n kẹ̀yìn sí tẹmpili OLUWA, wọ́n sì kọjú sí ìlà oòrùn. Wọ́n ń foríbalẹ̀ wọ́n ń bọ oòrùn.
17Ó bi mí pé: “Ọmọ eniyan, ṣé o rí ohun tí wọn ń ṣe yìí? Ṣé nǹkan ìríra tí àwọn ọmọ ilé Juda ń ṣe níhìn-ín kò jọ wọ́n lójú ni wọ́n ṣe mú kí ìwà ìkà kún ilẹ̀ yìí, tí wọn ń mú mi bínú sí i? Wò bí wọ́n ti ń tàbùkù mi, tí wọn ń fín mi níràn. 18Nítorí náà, n óo bínú sí wọn, n kò ní fojú fo iṣẹ́ wọn, n kò sì ní ṣàánú wọn. Wọ́n ìbáà máa kígbe sí mi létí, n kò ní dá wọn lóhùn.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ISIKIẸLI 8: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: