ISIKIẸLI 4

4
Isikiẹli Gbé Òfin Jáde lórí Ìwà Ìbàjẹ́ ní Jerusalẹmu
1OLUWA ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, mú bulọọku kan kí o gbé e ka iwájú rẹ, kí o sì ya àwòrán ìlú Jerusalẹmu sórí rẹ̀. 2Kó àwọn nǹkan tí wọ́n fi ń dóti ìlú tì í. Bu yẹ̀ẹ̀pẹ̀ sí i lẹ́gbẹ̀ẹ́ kí ọ̀nà dé ibẹ̀. Fi àgọ́ àwọn jagunjagun sí i, kí o wá gbẹ́ kòtò ńlá yí i ká. 3Wá irin pẹlẹbẹ kan tí ó fẹ̀, kí o gbé e sí ààrin ìwọ ati ìlú náà, kí ó dàbí ògiri onírin. Dojú kọ ọ́ bí ìlú tí a gbógun tì; kí o ṣebí ẹni pé ò ń gbógun tì í. Èyí yóo jẹ́ àmì fún ilé Israẹli.
4“Lẹ́yìn náà, fi ẹ̀gbẹ́ rẹ òsì dùbúlẹ̀, kí o sì di ìjìyà àwọn ọmọ ilé Israẹli lé ara rẹ lórí. O óo ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún iye ọjọ́ tí o bá fi dùbúlẹ̀. 5Mo ti fún ọ ní irinwo ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390) láti fi ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli. Èyí ni iye ọdún tí wọ́n fi dẹ́ṣẹ̀. 6Nígbà tí o bá parí iye ọjọ́ yìí, o óo fi ẹ̀gbẹ́ rẹ ọ̀tún lélẹ̀, o óo sì fi ogoji ọjọ́ ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Juda; ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tí o óo fi dùbúlẹ̀ dúró fún ọdún kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fi dẹ́ṣẹ̀.
7“Lẹ́yìn náà, kọjú sí Jerusalẹmu, ìlú tí a gbógun tì, ká aṣọ kúrò ní apá rẹ kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí i. 8Wò ó! N óo dè ọ́ lókùn mọ́lẹ̀, tí o kò fi ní lè yí ẹ̀gbẹ́ pada títí tí o óo fi parí iye ọjọ́ tí o níláti fi gbé ogun tì í.
9“Mú alikama ati ọkà baali, ẹ̀wà ati lẹntili, jéró ati ọkà sipẹliti, kí o kó wọn sinu ìkòkò kan, kí o sì fi wọ́n ṣe burẹdi fún ara rẹ. Òun ni o óo máa jẹ fún irinwo ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390), tí o óo fi fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀. 10Wíwọ̀n ni o óo máa wọn oúnjẹ tí o óo máa jẹ, ìwọ̀n oúnjẹ òòjọ́ rẹ yóo jẹ́ ogún ṣekeli, ẹ̀ẹ̀kan lojumọ ni o óo sì máa jẹ ẹ́. 11Wíwọ̀n ni o óo máa wọn omi tí o óo máa mu pẹlu; ìdá mẹfa òṣùnwọ̀n hini ni omi tí o óo máa mu ní ọjọ́ kan, ẹ̀ẹ̀kan lojumọ ni o óo sì máa mu ún. 12O óo jẹ ẹ́ bí àkàrà ọkà baali dídùn; ìgbẹ́ eniyan ni o óo máa fi dá iná tí o óo máa fi dín in lójú wọn.”
13OLUWA ní: “Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli yóo ṣe máa jẹ oúnjẹ wọn ní àìmọ́, láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí òun óo lé wọn sí.”
14Mo bá dáhùn pé, “Háà! OLUWA Ọlọrun, n kò sọ ara mi di aláìmọ́ rí láti ìgbà èwe mi títí di ìsinsìnyìí, n kò jẹ òkú ẹran rí, tabi ẹran tí ẹranko pa, bẹ́ẹ̀ ni ẹran àìmọ́ kankan kò kan ẹnu mi rí.”
15OLUWA bá wí fún mi pé, “Kò burú, n óo jẹ́ kí o fi ìgbẹ́ mààlúù dáná láti fi dín àkàrà rẹ, dípò ìgbẹ́ eniyan.”
16Ó tún fi kun fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, n óo mú kí oúnjẹ wọ́n ní Jerusalẹmu tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ìbẹ̀rù ni wọn óo máa fi wá oúnjẹ tí wọn óo máa jẹ, wíwọ̀n ni wọn óo sì máa wọn omi mu pẹlu ìpayà. 17N óo ṣe bẹ́ẹ̀ kí wọ́n lè ṣe aláìní oúnjẹ ati omi, kí wọ́n lè máa wo ara wọn pẹlu ìpayà, kí wọ́n sì parun nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ISIKIẸLI 4: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀