“O kò gbọdọ̀ lọ́wọ́ sí àhesọ tí kò ní òtítọ́ ninu. O kò gbọdọ̀ bá eniyan burúkú pa ìmọ̀ pọ̀ láti jẹ́rìí èké. O kò gbọdọ̀ bá ọ̀pọ̀ eniyan kẹ́gbẹ́ láti ṣe ibi, tabi kí o tẹ̀lé ọ̀pọ̀ eniyan láti jẹ́rìí èké tí ó lè yí ìdájọ́ po. O kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju sí talaka lórí ẹjọ́ rẹ̀. “Bí o bá pàdé akọ mààlúù ọ̀tá rẹ tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tí ń ṣìnà lọ, o níláti fà á pada wá fún un. Bí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹni tí ó kórìíra rẹ, tí ẹrù wó kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà mọ́lẹ̀, tí kò lè lọ mọ́, o kò gbọdọ̀ gbójú kúrò kí o fi sílẹ̀ níbẹ̀, o níláti bá a sọ ẹrù náà kalẹ̀. “O kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ òdodo tí ó tọ́ sí talaka po nígbà tí ó bá ní ẹjọ́. O kò gbọdọ̀ fi ẹ̀sùn èké kan ẹnikẹ́ni, o kò sì gbọdọ̀ pa aláìṣẹ̀ tabi olódodo nítorí pé, èmi, OLUWA kò ní dá eniyan burúkú láre. O kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a máa fọ́ àwọn aláṣẹ lójú, kì í jẹ́ kí wọn rí ẹ̀tọ́, a sì máa mú kí wọn sọ ẹjọ́ aláre di ẹ̀bi. “O kò gbọdọ̀ pọ́n àlejò lójú, ẹ mọ̀ bí ọkàn àlejò ti rí, nítorí ẹ̀yin pàápàá jẹ́ àlejò rí ní ilẹ̀ Ijipti. “Ọdún mẹfa ni kí o fi máa fúnrúgbìn sórí ilẹ̀ rẹ kí o sì fi máa kórè àwọn ohun ọ̀gbìn inú rẹ̀. Ṣugbọn ní ọdún keje, o gbọdọ̀ fi oko náà sílẹ̀ kí ó sinmi, kí àwọn talaka ninu yín náà lè rí oúnjẹ jẹ, kí àwọn ẹranko sì jẹ ninu èyí tí àwọn talaka bá jẹ kù. Bẹ́ẹ̀ ni o gbọdọ̀ ṣe ọgbà àjàrà rẹ, ati ọgbà olifi rẹ pẹlu. “Ọjọ́ mẹfa ni kí o fi ṣe iṣẹ́, ṣugbọn ní ọjọ́ keje, kí o sinmi; àtìwọ ati akọ mààlúù rẹ, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ; kí ara lè tu ọmọ iranṣẹbinrin rẹ ati àlejò rẹ. “Máa ṣe akiyesi gbogbo ohun tí mo ti sọ fún ọ, má sì ṣe bọ oriṣa kankan, má tilẹ̀ jẹ́ kí n gbọ́ orúkọ wọn lẹ́nu rẹ.
Kà ẸKISODU 23
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ẸKISODU 23:1-13
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò