ẸKISODU 2:5-6

ẸKISODU 2:5-6 YCE

Láìpẹ́, ọmọbinrin Farao lọ wẹ̀ ní odò náà, àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ sì ń rìn káàkiri etídò. Ó rí apẹ̀rẹ̀ náà láàrin koríko, ó bá rán iranṣẹbinrin rẹ̀ lọ gbé apẹ̀rẹ̀ náà. Nígbà tí ó ṣí i, ó rí ọmọ kan ninu rẹ̀, ọmọ náà ń sọkún. Àánú ṣe é, ó wí pé, “Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Heberu nìyí.”