ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 24:14-16

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 24:14-16 YCE

Ṣugbọn mo jẹ́wọ́ ohun kan fun yín: lóòótọ́ ni mò ń sin Ọlọrun àwọn baba wa ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀. Mo gba gbogbo ohun tí ó wà ninu ìwé Òfin ati ninu ìwé àwọn wolii. Mo sì ń wojú Ọlọrun nítorí pé mo ní ìrètí kan náà tí àwọn ará ibí yìí pàápàá tí wọn ń rojọ́ mi ní, pé gbogbo òkú ni yóo jinde, ati ẹni rere ati ẹni burúkú. Ìdí nìyí tí mo fi ń sa ipá mi kí ọkàn mi lè jẹ́ mi lẹ́rìí pé inú mi mọ́ sí Ọlọrun ati eniyan nígbà gbogbo.