ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 2:37-40
ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 2:37-40 YCE
Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́, ọ̀rọ̀ náà gún wọn lọ́kàn. Wọ́n wá bi Peteru ati àwọn aposteli yòókù pé, “Ẹ̀yin ará, kí ni kí á wá ṣe?” Peteru dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ronupiwada, kí á ṣe ìrìbọmi fún ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ní orúkọ Kristi. A óo sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín, ẹ óo wá gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́. Nítorí ẹ̀yin ni a ṣe ìlérí yìí fún, ati àwọn ọmọ yín ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn; a ṣe é fún gbogbo ẹni tí Oluwa Ọlọrun wa bá pè.” Ó tún bá wọn sọ̀rọ̀ pupọ, ó ń rọ̀ wọ́n gidigidi, pé, “Ẹ gba ara yín kúrò ninu ìyà tí ìran burúkú yìí yóo jẹ.”


