ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 10:44-46

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 10:44-46 YCE

Bí Peteru ti ń sọ̀rọ̀ báyìí lọ́wọ́, kò tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń sọ, bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé gbogbo àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Ẹnu ya àwọn onigbagbọ tí wọ́n jẹ́ Juu tí wọ́n bá Peteru wá nítorí àwọn tí kì í ṣe Juu rí ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ gbà lọ́fẹ̀ẹ́ ati lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Wọ́n gbọ́ tí wọn ń fi oríṣìíríṣìí èdè sọ̀rọ̀, tí wọn ń yin Ọlọrun fún iṣẹ́ ńlá rẹ̀. Peteru bá bèèrè pé