SAMUẸLI KEJI 23:3-4

SAMUẸLI KEJI 23:3-4 YCE

Ọlọrun Israẹli ti sọ̀rọ̀, Àpáta Israẹli ti wí fún mi pé, ‘Ẹni yòówù tí ó bá fi òtítọ́ jọba, tí ó ṣe àkóso pẹlu ìbẹ̀rù Ọlọrun, a máa tàn sí wọn bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, bí oòrùn tí ó ń ràn ní òwúrọ̀ kutukutu, ní ọjọ́ tí kò sí ìkùukùu; ó dàbí òjò tí ń mú kí koríko hù jáde láti inú ilẹ̀.’