SAMUẸLI KEJI 22
22
Orin Ìṣẹ́gun Tí Dafidi Kọ
(O. Daf 18)
1Nígbà tí OLUWA gba Dafidi lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ati lọ́wọ́ Saulu, Dafidi kọ orin yìí sí OLUWA pé:
2“OLUWA ni àpáta mi,
ààbò mi, ati olùgbàlà mi;
3Ọlọrun mi, àpáta mi,
ọ̀dọ̀ ẹni tí mo sá pamọ́ sí.
Àpáta mi ati ìgbàlà mi,
ààbò mi ati ibi ìpamọ́ mi,
olùgbàlà mi, ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ ìwà ipá.
4Mo ké pe OLUWA, ẹni tí ìyìn yẹ,
Ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.
5“Ikú yí mi káàkiri, bí ìgbì omi;
ìparun sì bò mí mọ́lẹ̀ bíi ríru omi;
6isà òkú ya ẹnu sílẹ̀ dè mí,
ewu ikú sì dojú kọ mí.
7Ninu ìpọ́njú mi, mo ké pe OLUWA
mo ké pe Ọlọrun mi,
ó gbọ́ ohùn mi láti inú tẹmpili rẹ̀;
ó sì tẹ́tí sí igbe mi.
8“Ayé mì, ó sì wárìrì;
ìpìlẹ̀ àwọn ọ̀run sì wárìrì,
ó mì tìtì, nítorí ibinu Ọlọrun.
9Èéfín jáde láti ihò imú rẹ̀,
iná ajónirun sì jáde láti ẹnu rẹ̀;
ẹ̀yinná tí ó pọ́n rẹ̀rẹ̀ ń ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ jáde.
10Ó tẹ àwọn ọ̀run ba, ó sì sọ̀kalẹ̀;
ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.
11Ó gun orí Kerubu, ó fò,
afẹ́fẹ́ ni ó fi ṣe ìyẹ́ tí ó fi ń fò.
12Ó fi òkùnkùn bo ara,
ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn,
tí ó sì kún fún omi ni ó fi ṣe ìbòrí.
13Ẹ̀yinná tí ń jó ń jáde,
láti inú ìmọ́lẹ̀ tí ó wà níwájú rẹ̀.
14“OLUWA sán ààrá láti ọ̀run wá,
ayé sì gbọ́ ohùn ọ̀gá ògo.
15Ó ta ọpọlọpọ ọfà, ó sì tú wọn ká.
Ó tan mànàmáná, wọ́n sì ń sá.
16Ìsàlẹ̀ òkun di gbangba, ìpìlẹ̀ ayé sì ṣí sílẹ̀,
nígbà tí OLUWA bá wọn wí,
tí ó sì fi ibinu jágbe mọ́ wọn.
17“OLUWA nawọ́ sílẹ̀ láti òkè wá, ó dì mí mú,
ó fà mí jáde kúrò ninu omi jíjìn.
18Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi, tí ó lágbára;
ati lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra mi;
nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ.
19Nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú; wọ́n gbógun tì mí,
ṣugbọn OLUWA dáàbò bò mí.
20Ó ràn mí lọ́wọ́,
ó kó mi yọ ninu ewu,
ó sì gbà mí là,
nítorí pé inú rẹ̀ dùn sí mi.
21“OLUWA fún mi ní èrè òdodo mi,
ó san ẹ̀san fún mi, nítorí pé mo jẹ́ aláìlẹ́bi.
22Nítorí pé mo pa àwọn òfin OLUWA mọ́,
n kò sì ṣe agídí, kí n yipada kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun mi.
23Mo ti tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀,
n kò sì ṣe àìgbọràn sí àwọn ìlànà rẹ̀.
24N kò lẹ́bi níwájú rẹ̀,
mo sì ti yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀ dídá.
25Nítorí náà ni OLUWA ṣe san án fún mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,
ati gẹ́gẹ́ bí mo ti jẹ́ mímọ́ níwájú rẹ̀.
26“OLUWA, ò máa ṣe olóòótọ́ sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá hu ìwà òtítọ́ sí ọ;
ò sì máa fi ara rẹ hàn bí aláìlẹ́bi, fún gbogbo àwọn tí kò ní ẹ̀bi.
27Ọlọrun, mímọ́ ni ọ́, sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá mọ́,
ṣugbọn o kórìíra gbogbo àwọn eniyan burúkú.
28Ò máa gba àwọn onírẹ̀lẹ̀,
o dójú lé àwọn agbéraga, láti rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.
29“OLUWA, ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ mi,
ìwọ ni o sọ òkùnkùn mi di ìmọ́lẹ̀.
30Nípa agbára rẹ, mo lè ṣẹgun àwọn ọ̀tá mi,
mo sì lè fo odi kọjá.
31Ní ti Ọlọrun yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀,
òtítọ́ ni ìlérí OLUWA,
ó sì jẹ́ apata fun gbogbo àwọn tí wọ́n bá sápamọ́ sábẹ́ ààbò rẹ̀.
32Ta ni Ọlọrun bí kò ṣe OLUWA?
Ta sì ni àpáta ààbò bí kò ṣe Ọlọrun wa?
33Ọlọrun yìí ni ààbò mi tí ó lágbára,
ó mú gbogbo ewu kúrò ní ọ̀nà mi.
34Ó fún ẹsẹ̀ mi lókun láti sáré bí àgbọ̀nrín,
ó sì mú kí n wà ní àìléwu lórí àwọn òkè.
35Ó kọ́ mi ní ogun jíjà,
tóbẹ́ẹ̀ tí mo lè lo ọrun idẹ.#Hab 3:19
36“O fún mi ní àpáta ìgbàlà rẹ,
ìrànlọ́wọ́ rẹ ni ó sọ mí di ẹni ńlá.
37Ìwọ ni o kò jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tá tẹ̀ mí,
bẹ́ẹ̀ ni o kò jẹ́ kí ẹsẹ̀ mí kí ó yẹ̀.
38Mo lépa àwọn ọ̀tá mi,
mo sì ṣẹgun wọn
n kò pada lẹ́yìn wọn títí tí mo fi pa wọ́n run.
39Mo pa wọ́n run, mo bì wọ́n lulẹ̀;
wọn kò sì lè dìde mọ́;
wọ́n ṣubú lábẹ́ ẹsẹ̀ mi.
40Ìwọ ni o fún mi lágbára láti jagun,
o jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi rì lábẹ́ mi.
41O mú kí àwọn ọ̀tá mi sá fún mi,
mo sì pa àwọn tí wọ́n kórìíra mi run.
42Wọ́n wá ìrànlọ́wọ́ káàkiri,
ṣugbọn kò sí ẹni tí ó lè gbà wọ́n;
wọ́n pe OLUWA,
ṣugbọn kò dá wọn lóhùn.
43Mo fọ́ wọn túútúú, wọ́n sì dàbí erùpẹ̀ ilẹ̀;
mo tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n sì dàbí ẹrọ̀fọ̀ lójú títì.
44“Ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ ìjà àwọn eniyan mi,
o sì mú kí ìjọba mi dúró lórí àwọn orílẹ̀ èdè;
àwọn eniyan tí n kò mọ̀ rí di ẹni tí ó ń sìn mí.
45Àwọn àjèjì ń wólẹ̀ níwájú mi,
ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí wọ́n bá ti gbúròó mi, ni wọ́n ń mú àṣẹ mi ṣẹ.
46Ẹ̀rù ba àwọn àjèjì,
wọ́n gbọ̀n jìnnìjìnnì jáde ní ibi ààbò wọn.
47“OLUWA wà láàyè,
ìyìn ni fún àpáta ààbò mi.
Ẹ gbé Ọlọrun mi ga,
ẹni tíí ṣe àpáta ìgbàlà mi.
48Ọlọrun ti jẹ́ kí n gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi,
ó ti tẹ orí àwọn orílẹ̀-èdè ba lábẹ́ mi;
49ó sì fà mí yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.
“OLUWA, ìwọ ni o gbé mi ga ju àwọn ọ̀tá mi lọ,
o sì dáàbò bò mí, lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá.
50Nítorí náà, n óo máa yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,
n óo máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.
51Ọlọrun fi ìṣẹ́gun ńlá fún ọba rẹ̀,
ó sì fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ han ẹni tí ó fi àmì òróró yàn,
àní Dafidi ati arọmọdọmọ rẹ̀ laelae!”#Rom 15:9
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
SAMUẸLI KEJI 22: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Ìsàmì-sí
Pín
Daako

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010