Ní ọjọ́ kan Eliṣa lọ sí Ṣunemu, níbi tí obinrin ọlọ́rọ̀ kan ń gbé; obinrin náà sì pe Eliṣa wọlé kí ó wá jẹun. Láti ìgbà náà, ilé obinrin yìí ni Eliṣa ti máa ń jẹun ní Ṣunemu. Obinrin náà sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Mo wòye pé ọkunrin tí ó ń wá síbí yìí jẹ́ ẹni mímọ́ Ọlọ́run. Jẹ́ kí á ṣe yàrá kékeré kan sí òkè ilé wa, kí á gbé ibùsùn, tabili, àga ati fìtílà sibẹ, kí ó lè máa dé sibẹ nígbàkúùgbà tí ó bá wá síbí.”
Ní ọjọ́ kan tí Eliṣa pada lọ sí Ṣunemu, ó wọ inú yàrá náà lọ láti sinmi. Ó bá rán Gehasi iranṣẹ rẹ̀ kí ó pe obinrin náà wá. Nígbà tí ó wọlé ó dúró níwájú Eliṣa. Eliṣa sọ fún Gehasi kí ó bèèrè lọ́wọ́ obinrin náà ohun tí ó fẹ́ kí òun ṣe fún un, fún gbogbo nǹkan tí ó ti ṣe fún àwọn. Ó ní, bóyá ó fẹ́ kí òun sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún ọba ni tabi fún balogun? Obinrin náà dáhùn pé ààrin àwọn eniyan òun ni òun ń gbé.
Eliṣa bá bèèrè lọ́wọ́ Gehasi pé, “Kí ni mo lè ṣe fún un nígbà náà?”
Gehasi ní, “Kò bímọ, ọkọ rẹ̀ sì ti di arúgbó.”
Eliṣa bá rán Gehasi kí ó pe obinrin náà wá. Nígbà tí ó dé, ó dúró ní ẹnu ọ̀nà. Eliṣa sọ fún un pé, “Níwòyí àmọ́dún, o óo fi ọwọ́ rẹ gbé ọmọkunrin.”
Obinrin náà dáhùn pé, “Háà! Oluwa mi, eniyan Ọlọrun ni ọ́, nítorí náà má ṣe parọ́ fún iranṣẹbinrin rẹ.”
Ṣugbọn obinrin náà lóyún ó sì bí ọmọkunrin ní akoko náà ní ọdún tí ó tẹ̀lé e gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Eliṣa.
Ní ọjọ́ kan, lẹ́yìn tí ọmọ náà dàgbà, ó lọ bá baba rẹ̀ ninu oko níbi tí wọ́n ti ń kórè. Lójijì, ó kígbe pe baba rẹ̀, ó ní, “Orí mi! Orí mi!”
Baba rẹ̀ sì sọ fún iranṣẹ kan kí ó gbé ọmọ náà lọ sọ́dọ̀ ìyá rẹ̀. Nígbà tí iranṣẹ náà gbé ọmọ náà dé ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ gbé e lé ẹsẹ̀ títí ọmọ náà fi kú ní ọ̀sán ọjọ́ náà. Obinrin náà bá gbé òkú ọmọ náà lọ sí yàrá Eliṣa, ó tẹ́ ẹ sí orí ibùsùn rẹ̀, ó ti ìlẹ̀kùn, ó sì jáde. Ó kígbe pe ọkọ rẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́ rán iranṣẹ kan sí mi pẹlu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan. Mo fẹ́ sáré lọ rí eniyan Ọlọ́run, n óo pada dé kíákíá.”
Ọkọ rẹ̀ bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló dé tí o fi fẹ́ lọ rí i lónìí? Òní kì í ṣe ọjọ́ oṣù tuntun tabi ọjọ́ ìsinmi.”
Ó sì dáhùn pé, “Kò séwu.”