ÀWỌN ỌBA KEJI 18
18
Hesekaya, Ọba Juda
(2Kron 29:1-2; 31:1)
1Ní ọdún kẹta tí Hoṣea, ọmọ Ela, jọba ní Israẹli ni Hesekaya, ọmọ Ahasi jọba ní Juda. 2Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni nígbà tí ó jọba, ó sì jọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkandinlọgbọn. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Abi, ọmọ Sakaraya. 3Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, nítorí pé ó tẹ̀lé àpẹẹrẹ Dafidi, baba ńlá rẹ̀. 4Ó wó gbogbo àwọn pẹpẹ oriṣa, ó wó gbogbo àwọn òpó tí wọ́n fi òkúta ṣe, ó sì gé gbogbo àwọn ère oriṣa Aṣera. Ó rún ejò idẹ tí Mose ṣe, tí wọn ń pè ní Nehuṣitani nítorí pé títí di àkókò náà àwọn ọmọ Israẹli a máa sun turari sí i.#Nọm 21:9 5Hesekaya ní igbagbọ ninu OLUWA Ọlọrun Israẹli. Juda kò sì ní ọba mìíràn tí ó dà bíi rẹ̀, yálà ṣáájú rẹ̀ ni, tabi lẹ́yìn rẹ̀. 6Ó jẹ́ olóòótọ́ sí OLUWA, kò yapa kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ṣugbọn ó fi tọkàntọkàn pa àwọn òfin tí OLUWA fún Mose mọ́. 7OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ó sì ń ṣe àṣeyọrí ninu gbogbo ohun tí ó ń ṣe. Ó gba ara rẹ̀ lọ́wọ́ ọba Asiria, ó di òmìnira, ó kọ̀ kò sìn ín mọ́. 8Ó ṣẹgun àwọn ará Filistia, títí dé ìlú Gasa ati agbègbè tí ó yí i ká, ati ilé ìṣọ́ wọn, ati ìlú olódi wọn.
9Ní ọdún kẹrin tíí Hesekaya jọba, tíi ṣe ọdún keje tí Hoṣea, ọmọ Ela, jọba lórí Israẹli, Ṣalimaneseri, ọba Asiria, gbógun ti Samaria, ó sì dó tì í. 10Nígbà tí ó ti di ọdún kẹta tí ó ti dó ti Samaria, ó ṣẹgun rẹ̀. Èyí jẹ́ ọdún kẹfa tí Hesekaya jọba, ati ọdún kẹsan-an tí Hoṣea jọba. 11Ọba Asiria kó àwọn ọmọ Israẹli ní ìgbèkùn lọ sí Asiria, ó sì kó wọn sí ìlú Hala ati Habori tí ó wà ní agbègbè odò Gosani ati sí àwọn ìlú àwọn ará Media.
12Ogun kó Samaria nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli kò pa òfin OLUWA Ọlọrun wọn mọ́, wọ́n si da majẹmu tí OLUWA bá wọn dá. Wọn kò pa àwọn òfin tí OLUWA fún Mose, iranṣẹ rẹ̀ mọ́, wọn kò sì gbọ́ràn.
Asiria Halẹ̀ Mọ́ Jerusalẹmu
(2Kron 32:1-19; Ais 36:1-22)
13Ní ọdún kẹrinla tí Hesekaya jọba ní Juda, ni Senakeribu, ọba Asiria, gbógun ti àwọn ìlú olódi Juda, ó sì ṣẹgun wọn. 14Hesekaya ranṣẹ sí Senakeribu, ọba Asiria, tí ó wà ní Lakiṣi nígbà náà, ó ní: “Mo ti ṣẹ̀, jọ̀wọ́ dá ọwọ́ ogun rẹ dúró; n óo sì san ohunkohun tí o bá bèèrè.” Ọba náà sì bèèrè fún ọọdunrun ìwọ̀n talẹnti fadaka ati ọgbọ̀n ìwọ̀n talẹnti wúrà lọ́wọ́ Hesekaya ọba Juda. 15Hesekaya bá kó gbogbo fadaka tí ó wà ninu ilé OLUWA ati ti inú ilé ìṣúra tí ó wà ní ààfin ranṣẹ sí i. 16Ó sì ṣí wúrà tí ó wà lára ìlẹ̀kùn ilé OLUWA ati wúrà tí òun tìkararẹ̀ fi bo àwọn òpó ìlẹ̀kùn, ó kó wọn ranṣẹ sí Senakeribu. 17Ọba Asiria rán àwọn ọ̀gágun rẹ̀: Tatani, Rabusarisi ati Rabuṣake pẹlu ọpọlọpọ ọmọ ogun láti Lakiṣi láti gbógun ti Hesekaya ní Jerusalẹmu. Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu wọ́n dúró sí ibi ọ̀nà tí àwọn tí wọn ń hun aṣọ tí ń ṣiṣẹ́, lẹ́bàá kòtò omi tí ń ṣàn wá láti adágún omi tí ó wà ninu ìlú lápá òkè. 18Nígbà tí wọ́n ké sí Hesekaya ọba, Eliakimu, ọmọ Hilikaya tí ó ń ṣe àkóso ààfin, ati Ṣebina akọ̀wé ọba, ati Joa ọmọ Asafu, tí ń ṣe àkóso ìwé ìrántí ni wọ́n jáde sí wọn. 19Rabuṣake ní, “Ẹ sọ fún Hesekaya pé, ọba ńlá, ọba ilẹ̀ Asiria ní kí ni ó gbẹ́kẹ̀lé? 20Ṣé ó rò pé ọ̀rọ̀ lásán lè dípò ọgbọ́n ati agbára ogun ni? Ó ní, ta ni Hesekaya gbẹ́kẹ̀lé tí ó fi ń dìtẹ̀ mọ́ òun? 21Ṣé Ijipti ni ó gbójú lé pé yóo ran òun lọ́wọ́? Ó ní ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí ẹni tí ó ń fi igi tí kò ní agbára ṣe ọ̀pá ìtilẹ̀. Tí igi náà bá dá, yóo gún un lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ijipti rí sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbẹ́kẹ̀ wọn lé e.
22“Ṣugbọn tí ẹ bá sọ fún mi pé ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA Ọlọrun yín, ṣebí àwọn ibi ìrúbọ ati àwọn pẹpẹ Ọlọrun náà ni Hesekaya ti bàjẹ́, tí ó sì sọ fún àwọn ará Juda ati Jerusalẹmu pé, ‘Níwájú pẹpẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu nìkan ni kí ẹ ti máa sìn.’ 23Nisinsinyii, ẹ wá ṣe àdéhùn pẹlu ọba Asiria, oluwa mi. N óo fun yín ní ẹgbaa (2,000) ẹṣin bí ẹ bá lè rí ẹgbaa (2,000) eniyan tí yóo gùn wọ́n. 24Ẹ kò lè ṣẹgun ẹni tí ó kéré jùlọ ninu àwọn ọ̀gágun ọba Asiria, sibẹ o rò pé àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin ọba Ijipti yóo ràn ọ́ lọ́wọ́. 25Ṣé o rò pé lásán ni mo wá láti pa ilẹ̀ yìí run, láìsí ìrànlọ́wọ́ OLUWA? OLUWA fúnra rẹ̀ ni ó sọ fún mi pé kí n wá pa ilẹ̀ yìí run.”
26Nígbà náà ni Eliakimu, ọmọ Hilikaya ati Ṣebina ati Joa sọ fún Rabuṣake pé, “Jọ̀wọ́, bá àwa iranṣẹ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Aramaiki nítorí pé a gbọ́. Má sọ èdè Heberu mọ́, nítorí pé àwọn tí wọ́n wà lórí odi ń gbọ́ ohun tí ò ń sọ.”
27Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Ṣé ẹ rò pé ẹ̀yin ati ọba nìkan ni ọba Asiria rán mi sí ni? Rárá, àwọn tí wọ́n wà lórí odi náà wà lára àwọn tí mò ń bá sọ̀rọ̀. Àwọn náà yóo jẹ ìgbẹ́ ara wọn tí wọn yóo sì mu ìtọ̀ ara wọn bí ẹ̀yin náà.”
28Nígbà náà ni Rabuṣake kígbe sókè rara ní èdè Heberu tíí ṣe èdè àwọn ará Juda ó ní, “Ẹ gbọ́ ohun tí ọba Asiria ń sọ fun yín; 29ó ní òun ń kìlọ̀ fun yín pé kí ẹ má jẹ́ kí Hesekaya tàn yín jẹ, kò lè gbà yín sílẹ̀. 30Ó ní kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ó mú ki ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA kí ó máa sọ pé OLUWA yóo gbà yín sílẹ̀, ati pé kò ní jẹ́ kí ogun Asiria kó ìlú yín. 31Ẹ má ṣe gbọ́ ti Hesekaya; nítorí pé ọba Asiria ní kí ẹ jáde wá kí ẹ bá òun ṣe àdéhùn alaafia; òun yóo gbà yín láàyè láti máa jẹ èso àjàrà ninu ọgbà àjàrà yín. Ẹ óo máa jẹ èso orí igi ọ̀pọ̀tọ́ yín, ẹ óo sì máa mu omi láti inú kànga yín; 32títí di ìgbà tí òun óo fi ko yín lọ sí ilẹ̀ mìíràn tí yóo dàbí tiyín, ilẹ̀ tí ó kún fún ọkà ati waini, ilẹ̀ tí ó kún fún oúnjẹ ati ọgbà àjàrà, ilẹ̀ tí ó kún fún igi olifi ati oyin, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ má baà kú. Ẹ má jẹ́ kí Hesekaya tàn yín, kí ẹ máa rò pé OLUWA yóo gbà yín. 33Ṣé ọlọrun àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn gbà wọ́n lọ́wọ́ ọba Asiria? 34Níbo ni ọlọrun Hamati ati ti Aripadi wà? Níbo ni àwọn ọlọrun Sefafaimu, ati ti Hena ati ti Ifa wà? Ṣé wọ́n gba Samaria lọ́wọ́ mi? 35Nígbà wo ni ọ̀kan ninu àwọn ọlọrun orílẹ̀-èdè wọnyi gba orílẹ̀-èdè wọn lọ́wọ́ ọba Asiria rí, tí OLUWA yóo fi gba Jerusalẹmu lọ́wọ́ mi?”
36Àwọn eniyan náà dákẹ́ jẹ́ẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba Hesekaya ti pàṣẹ fún wọn, wọn kò sọ ọ̀rọ̀ kankan. 37Nígbà náà ni Eliakimu, tí ń ṣe àkóso ààfin ati Ṣebina, akọ̀wé ọba, ati Joa, tí ń ṣe àkóso ìwé ìrántí fa aṣọ wọn ya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn, wọ́n sì lọ sọ ohun tí olórí ogun náà wí fun ọba.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÀWỌN ỌBA KEJI 18: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: