KRONIKA KEJI 5:13-14

KRONIKA KEJI 5:13-14 YCE

àwọn onífèrè ati àwọn akọrin pa ohùn pọ̀ wọ́n ń kọ orin ìyìn ati orin ọpẹ́ sí OLUWA). Wọ́n ń fi fèrè ati ìlù ati àwọn ohun èlò orin mìíràn kọrin ìyìn sí OLUWA pé: “OLUWA ṣeun, ìfẹ́ ńlá Rẹ̀ kò lópin.” Ìkùukùu kún inú tẹmpili OLUWA, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn alufaa kò fi lè ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn, nítorí ògo OLUWA tí ó kún ilé Ọlọrun.