KRONIKA KEJI 27
27
Jotamu, Ọba Juda
(2A. Ọba 15:32-38)
1Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni Jotamu nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹrindinlogun. Jeruṣa, ọmọ Sadoku ni ìyá rẹ̀. 2Ó ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA, gẹ́gẹ́ bíi Usaya, baba rẹ̀; àfi pé òun kò lọ sun turari ninu tẹmpili OLUWA. Ṣugbọn àwọn eniyan ń bá ìwà burúkú wọn lọ.
3Ó kọ́ ẹnu ọ̀nà òkè ilé OLUWA, ó sì tún ògiri Ofeli mọ. 4Ó kọ́ àwọn ìlú ní agbègbè olókè Juda ó sì kọ́ ibi ààbò ati ilé-ìṣọ́ ninu igbó lára òkè. 5Ó bá ọba àwọn ará Amoni jà, ó sì ṣẹgun wọn. Ní ọdún tí ó ṣẹgun wọn, wọ́n fún un ní ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ẹgbaarun (10,000) ìwọ̀n kori alikama ati ẹgbaarun (10,000) ìwọ̀n kori ọkà baali. Iye kan náà ni wọ́n fún un ní ọdún keji ati ọdún kẹta. 6Jotamu di alágbára nítorí ó rìn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ níwájú OLUWA Ọlọrun rẹ̀. 7Gbogbo nǹkan yòókù tí Jotamu ṣe ati àwọn ogun tí ó jà, ati àwọn nǹkan mìíràn tí ó tún ṣe ni a kọ sinu ìwé àwọn ọba Israẹli ati ti Juda. 8Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹrindinlogun ní Jerusalẹmu. 9Nígbà tí Jotamu kú, wọ́n sin ín ní ìlú Dafidi, Ahasi ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
KRONIKA KEJI 27: YCE
Ìsàmì-sí
Daako
Ṣe Àfiwé
Pín
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

: