ÀWỌN ỌBA KINNI 18:42-46
ÀWỌN ỌBA KINNI 18:42-46 YCE
Nígbà tí Ahabu lọ jẹun, Elija gun orí òkè Kamẹli lọ, ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó sì ki orí bọ ààrin orúnkún rẹ̀ mejeeji. Ó sọ fún iranṣẹ rẹ̀ pé kí ó lọ wo apá ìhà òkun. Iranṣẹ náà lọ, ó sì pada wá, ó ní, òun kò rí nǹkankan. Elija sọ fún un pé, “Tún lọ ní ìgbà meje.” Ní ìgbà keje tí ó pada dé, ó ní, “Mo rí ìkùukùu kan tí ń bọ̀ láti inú òkun, ṣugbọn kò ju àtẹ́lẹwọ́ lọ.” Elija pàṣẹ fún iranṣẹ rẹ̀ pé kí ó lọ sọ fún ọba, kí ó kó sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, kí ó sì sọ̀kalẹ̀ pada sí ilé kí òjò má baà ká a mọ́ ibi tí ó wà. Láìpẹ́, ìkùukùu bo gbogbo ojú ọ̀run, afẹ́fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́, òjò ńlá sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀. Ahabu kó sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sì pada lọ sí Jesireeli. Agbára OLUWA sọ̀kalẹ̀ sórí Elija, ó di àmùrè rẹ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí sáré lọ; ó sì ṣáájú Ahabu dé ẹnubodè Jesireeli.


