KRONIKA KINNI 8

8
Àwọn Ìran Bẹnjamini
1Bẹnjamini bí ọmọkunrin marun-un, Bela ni àkọ́bí, lẹ́yìn rẹ̀ ni Aṣibeli, 2lẹ́yìn rẹ̀, Ahara, lẹ́yìn rẹ̀, Nohahi, àbíkẹ́yìn rẹ̀ ni, Rafa.
3Àwọn ọmọ Bela ni: Adari, Gera, ati Abihudi, 4Abiṣua, Naamani, ati Ahoa, 5Gera, Ṣefufani, ati Huramu.
6Àwọn wọnyi ni ìran Ehudu: (Àwọn baálé baálé ninu ìran Geba, tí wọ́n kó lẹ́rú lọ sí ìlú Manahati): 7Naamani, Ahija ati Gera, tí ń jẹ́ Hegilamu, baba Usa, ati Ahihudu.
8Lẹ́yìn tí Ṣaharaimu ti kọ àwọn iyawo rẹ̀ mejeeji, Huṣimu ati Baara sílẹ̀, ó fẹ́ Hodeṣi, ó sì bímọ ní ilẹ̀ Moabu. 9Ọmọ meje ni Hodeṣi bí fún un: Jobabu, Sibia, Meṣa, ati Malikami, 10Jeusi, Sakia ati Mirima. Gbogbo wọn jẹ́ baálé baálé ní ìdílé wọn.
11Huṣimu náà bí ọmọkunrin meji fún un: Abitubu ati Elipaali.
12Elipaali bí ọmọkunrin mẹta: Eberi, Miṣamu ati Ṣemedi. Ṣemedi yìí ni ó kọ́ àwọn ìlú Ono, Lodi, ati gbogbo àwọn ìletò tí ó yí wọn ká.
Àwọn Ará Bẹnjamini Tí Wọ́n Wà Ní Gati ati Aijaloni
13Beraya ati Ṣema ni olórí àwọn ìdílé tí wọn ń gbé ìlú Aijaloni, àwọn sì ni wọ́n lé àwọn tí wọn ń gbé ìlú Gati tẹ́lẹ̀ kúrò; 14àwọn ọmọ Beraya ni: Ahio, Ṣaṣaki, ati Jeremotu, 15Sebadaya, Aradi, ati Ederi, 16Mikaeli, Iṣipa ati Joha.
Àwọn Ará Bẹnjamini ní Jerusalẹmu
17Àwọn ọmọ Elipaali ni: Sebadaya, Meṣulamu, Hiṣiki, ati Heberi, 18Iṣimerai, Isilaya ati Jobabu.
19Àwọn ọmọ Ṣimei ni: Jakimu, Sikiri, ati Sabidi; 20Elienai, Siletai, ati Elieli; 21Adaaya, Beraaya ati Ṣimirati;
22Àwọn ọmọ Ṣaṣaki nìwọ̀nyí: Iṣipani, Eberi, ati Elieli; 23Abidoni, Sikiri, ati Hanani; 24Hananaya, Elamu, ati Antotija; 25Ifideaya ati Penueli.
26Àwọn ọmọ Jerohamu ni: Ṣamṣerai, Ṣeharaya, ati Atalaya; 27Jaareṣaya, Elija ati Sikiri.
28Àwọn ni baálé baálé ní ìdílé wọn, ìjòyè ni wọ́n ní ìran wọn; wọ́n ń gbé Jerusalẹmu.
Àwọn Ará Bẹnjamini tí Wọ́n Wà ní Gibeoni ati Jerusalẹmu
29Jeieli, baba Gibeoni, ń gbé ìlú Gibeoni, Maaka ni orúkọ iyawo rẹ̀. 30Abidoni ni àkọ́bí rẹ̀, lẹ́yìn rẹ̀ ni ó bí: Suri, Kiṣi, Baali, ati Nadabu; 31Gedori, Ahio, Sekeri, ati 32Mikilotu (baba Ṣimea). Wọ́n ń bá àwọn arakunrin wọn gbé, àdúgbò wọn kọjú sí ara wọn ní Jerusalẹmu.
Ìdílé Saulu Ọba
33Neri ni baba Kiṣi, Kiṣi ni ó bí Saulu, Saulu sì bí àwọn ọmọkunrin mẹrin: Jonatani, Malikiṣua, Abinadabu, ati Eṣibaali. 34Jonatani bí Meribibaali, Meribibaali sì bí Mika.
35Mika bí ọmọkunrin mẹrin: Pitoni, Meleki, Tarea ati Ahasi. 36Ahasi ni baba Jehoada. Jehoada sì ni baba: Alemeti, Asimafeti, ati Simiri. Simiri ni ó bí Mosa. 37Mosa bí Binea; Binea bí Rafa, Rafa bí Eleasa, Eleasa sì bí Aseli.
38Aseli bí ọmọkunrin mẹfa: Asirikamu, Bokeru, Iṣimaeli, Ṣearaya, Ọbadaya, ati Hanani. Aseli ni baba gbogbo wọn. 39Eṣeki, arakunrin Aseli, bí ọmọ mẹta: Ulamu ni àkọ́bí rẹ̀, lẹ́yìn náà Jeuṣi, lẹ́yìn náà Elifeleti. 40Àwọn ọmọ Ulamu jẹ́ jagunjagun, tafàtafà ni wọ́n, wọ́n sì lókìkí. Àwọn ọmọ ati ọmọ ọmọ rẹ̀ pọ̀. Aadọjọ ni wọ́n, ara ẹ̀yà Bẹnjamini sì ni gbogbo wọ́n.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

KRONIKA KINNI 8: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀