KRONIKA KINNI 20

20
Dafidi Ṣẹgun Raba
(2Sam 12:26-31)
1Nígbà tí àkókò òtútù kọjá, ní àkókò tí àwọn ọba máa ń lọ jagun, Joabu gbógun ti ilẹ̀ Amoni; wọ́n dó ti ìlú Raba. Ṣugbọn Dafidi dúró ní Jerusalẹmu. Joabu gbógun ti Raba, ó sì ṣẹgun rẹ̀. 2Dafidi ṣí adé wúrà orí ọba wọn, ó sì rí i pé adé náà wọ̀n tó ìwọ̀n talẹnti wúrà kan, òkúta olówó iyebíye kan sì wà lára rẹ̀; wọ́n bá fi dé Dafidi lórí. Dafidi sì tún kó ọpọlọpọ ìkógun mìíràn ninu ìlú náà. 3Ó kó àwọn eniyan tí wọ́n wà ninu ìlú náà, ó sì ń fi wọ́n ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́: Àwọn kan ń lo ayùn, àwọn kan ń lo ọkọ́, àwọn mìíràn sì ń lo àáké. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe sí gbogbo àwọn ìlú Amoni. Òun ati àwọn eniyan rẹ̀ bá pada sí Jerusalẹmu.#2 Sam 11:1
Bíbá Àwọn Òmìrán Filistini Jagun
(2Sam 21:15-22)
4Lẹ́yìn náà, ogun bẹ́ sílẹ̀ ní Geseri, láàrin àwọn ará Filistia ati àwọn ọmọ Israẹli. Sibekai, ará Huṣati, pa ìran òmìrán kan, ará Filistia, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sipai, àwọn ará Israẹli bá ṣẹgun àwọn ará Filistia. 5Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ pẹlu àwọn ará Filistia, Elihanani, ọmọ Jairi, pa Lahimi, arakunrin Goliati, ará Gati, tí ọ̀kọ̀ rẹ̀ tóbi tó òpó òfì ìhunṣọ.#1 Sam 17:4-7
6Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ ní Gati. Ọkunrin gbọ̀ngbọ̀nràn kan wà níbẹ̀, ìka mẹfa ni ó ní ní ọwọ́ kọ̀ọ̀kan ati ní ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ òmìrán ni òun náà. 7Nígbà tí ó ń fi àwọn ọmọ Israẹli ṣe ẹlẹ́yà, Jonatani, ọmọ Ṣimea, arakunrin Dafidi bá pa á.
8Ìran òmìrán, ará Gati ni àwọn mẹtẹẹta; Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ ni ó sì pa wọ́n.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

KRONIKA KINNI 20: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀