KRONIKA KINNI 18

18
Àwọn Ogun tí Dafidi Jà ní Àjàṣẹ́gun
(2Sam 8:1-18)
1Lẹ́yìn náà, Dafidi gbógun ti àwọn Filistini, ó ṣẹgun wọn, ó sì jagun gba ìlú Gati ati àwọn ìletò agbègbè rẹ̀ lọ́wọ́ wọn. 2Dafidi ṣẹgun àwọn ará Moabu, wọ́n di iranṣẹ rẹ̀, wọ́n sì ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún un.
3Ó ṣẹgun Hadadeseri, ọba Siria ní Soba, ní agbègbè ilẹ̀ Hamati, bí Hadadeseri tí ń lọ fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ létí odò Yufurate. 4Dafidi gba ẹgbẹrun (1,000) kẹ̀kẹ́ ogun, ẹẹdẹgbaarin (7,000) ọmọ ogun ẹlẹ́ṣin, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ọmọ ogun lọ́wọ́ rẹ̀. Ó rọ́ àwọn ẹṣin náà lẹ́sẹ̀, ṣugbọn ó dá àwọn kan sí fún ọgọrun-un (100) kẹ̀kẹ́ ogun.
5Nígbà tí àwọn ará Siria wá láti Damasku, láti ran Hadadeseri, ọba Soba lọ́wọ́, Dafidi gbógun tì wọ́n, ó sì pa ẹgbaa mọkanla (22,000) ninu àwọn ọmọ ogun wọn. 6Dafidi fi àwọn ọmọ ogun ṣọ́ Siria ti Damasku, àwọn ará Siria di iranṣẹ Dafidi, wọ́n sì ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún un. OLUWA fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibi tí ó lọ. 7Dafidi gba àwọn apata wúrà tí wọ́n wà lọ́wọ́ àwọn iranṣẹ Hadadeseri, ó kó wọn lọ sí Jerusalẹmu. 8Ó kó ọpọlọpọ idẹ ní Tibihati ati Kuni, tí wọ́n wà lábẹ́ Hadadeseri. Idẹ yìí ni Solomoni fi ṣe agbada omi ńlá ati òpó ati àwọn ohun èlò idẹ fún ilé OLUWA.#1A. Ọba 7:40-47; 2Kron 4:11-18
9Nígbà tí Toi, ọba Hamati gbọ́ pé Dafidi ti ṣẹgun gbogbo àwọn ọmọ ogun Hadadeseri, ọba Soba, 10ó rán Hadoramu, ọmọ rẹ̀, pé kí ó lọ kí Dafidi ọba, kí ó sì bá a yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun tí ó ní lórí Hadadeseri, nítorí Hadadeseri ti bá Toi pàápàá jagun ní ọpọlọpọ ìgbà. Toi sì fi oríṣìíríṣìí ohun èlò wúrà, fadaka, ati idẹ ranṣẹ sí Dafidi. 11Dafidi yà wọ́n sí mímọ́ fún OLUWA, fún iṣẹ́ ìsìn pẹlu àwọn fadaka ati wúrà tí ó gbà lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti ṣẹgun: àwọn bíi Edomu ati Moabu, Amoni, Filistini ati Amaleki.
12Abiṣai, ọmọ Seruaya, ṣẹgun àwọn ará Edomu ní àfonífojì Iyọ̀, ó pa ẹgbaa mẹsan-an (18,000) ninu wọn. 13Ó fi àwọn ọmọ ogun sí Edomu, gbogbo àwọn ará Edomu sì di iranṣẹ Dafidi. OLUWA fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibi tí ó lọ.#O. Daf 60:Àkọlé
14Dafidi jọba lórí gbogbo Israẹli, ó ń dá ẹjọ́ òtítọ́, ó sì ń ṣe ẹ̀tọ́ fún gbogbo àwọn eniyan. 15Joabu, ọmọ Seruaya, ni Balogun rẹ̀, Jehoṣafati, ọmọ Ahiludi ni olùtọ́jú àwọn àkọsílẹ̀. 16Sadoku, ọmọ Ahitubu ati Ahimeleki ọmọ Abiatari ni alufaa. 17Ṣafiṣa ni akọ̀wé ilé ẹjọ́. Bẹnaya, ọmọ Jehoiada ní ń ṣe àkóso àwọn Kereti ati Peleti tí wọn ń ṣọ́ ọba, àwọn ọmọ Dafidi lọkunrin ni wọ́n sì wà ní àwọn ipò tí ó ga ninu ìjọba rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

KRONIKA KINNI 18: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀