1
Òwe 4:23
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
BMYO
Ju gbogbo nǹkan tókù lọ, pa ọkàn rẹ mọ́, nítorí òun ni orísun ìyè.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Òwe 4:23
2
Òwe 4:26
Kíyèsi ìrìn ẹsẹ̀ rẹ sì rìn ní àwọn ọ̀nà tí ó dára nìkan.
Ṣàwárí Òwe 4:26
3
Òwe 4:24
Mú àrékérekè kúrò ní ẹnu rẹ; sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ jìnnà réré sí ẹnu rẹ.
Ṣàwárí Òwe 4:24
4
Òwe 4:7
Ọgbọ́n ni ó ga jù; nítorí náà gba ọgbọ́n. Bí ó tilẹ̀ ná gbogbo ohun tí o ní, gba òye.
Ṣàwárí Òwe 4:7
5
Òwe 4:18-19
Ipa ọ̀nà olódodo dàbí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn tí ń tànmọ́lẹ̀ sí i títí ọjọ́ fi kanrí ṣùgbọ́n ọ̀nà ènìyàn búburú dàbí òkùnkùn biribiri; wọn kò mọ ohun tí ó ń mú wọn kọsẹ̀.
Ṣàwárí Òwe 4:18-19
6
Òwe 4:6
Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóò sì dáàbò bò ọ́, fẹ́ràn rẹ̀, yóò sì bojútó ọ.
Ṣàwárí Òwe 4:6
7
Òwe 4:13
Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ; tọ́jú u rẹ̀ dáradára nítorí òun ni ìyè rẹ.
Ṣàwárí Òwe 4:13
8
Òwe 4:14
Má ṣe gbé ẹsẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburú tàbí kí o rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi.
Ṣàwárí Òwe 4:14
9
Òwe 4:1
Tẹ́tí, ẹ̀yin ọmọ mi, sí ẹ̀kọ́ baba; fetísílẹ̀ kí o sì ní òye sí i.
Ṣàwárí Òwe 4:1
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò