Ó sì wí pé, “Èmi ti fẹ́ lọ sí ọ̀nà gbogbo ayé, nítorí náà jẹ́ alágbára kí o sì fi ara rẹ hàn bí ọkùnrin, kí o sì wòye ohun tí OLúWA Ọlọ́run rẹ béèrè, rìn ní ọ̀nà rẹ̀, kí o sì pa àṣẹ àti òfin rẹ̀ mọ́, àti ìdájọ́ rẹ, àti ẹ̀rí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé òfin Mose, nítorí kí ìwọ kí ó le è máa ṣe rere ní ohun gbogbo tí ìwọ ṣe, àti ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, kí OLúWA kí ó lè pa ìlérí rẹ̀ tí ó sọ nípa tèmi mọ́ pé: ‘Bí àwọn ọmọ rẹ bá kíyèsi ọ̀nà wọn, tí wọ́n bá sì fi gbogbo àyà wọn àti ọkàn wọn rìn níwájú mi ní òtítọ́, o kì yóò sì kùnà láti ní ọkùnrin kan lórí ìtẹ́ Israẹli.’