1
II. Kro 20:15
Bibeli Mimọ
YBCV
O si wipe, Ẹ tẹti silẹ, gbogbo Judah, ati ẹnyin olugbe Jerusalemu, ati iwọ Jehoṣafati ọba; Bayi li Oluwa wi fun nyin, Ẹ máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe fòya nitori ọ̀pọlọpọ enia yi; nitori ogun na kì iṣe ti nyin bikòṣe ti Ọlọrun.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí II. Kro 20:15
2
II. Kro 20:17
Ẹnyin kò ni ijà li ọ̀ran yi; ẹ tẹgun, ẹ duro jẹ, ki ẹ si ri igbala Oluwa lọdọ nyin, iwọ Juda ati Jerusalemu: ẹ máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe fòya: lọla, ẹ jade tọ̀ wọn: Oluwa yio si pẹlu nyin.
Ṣàwárí II. Kro 20:17
3
II. Kro 20:12
Ọlọrun wa! Iwọ kì o ha da wọn lẹjọ? nitori awa kò li agbara niwaju ọ̀pọlọpọ nla yi, ti mbọ̀ wá ba wa; awa kò si mọ̀ eyi ti awa o ṣe: ṣugbọn oju wa mbẹ lara rẹ.
Ṣàwárí II. Kro 20:12
4
II. Kro 20:21
O si ba awọn enia na gbero, o yàn awọn akọrin si Oluwa, ti yio ma yìn ẹwa ìwa-mimọ́ bi nwọn ti njade lọ niwaju ogun na, ati lati ma wipe, Ẹ yìn Oluwa: nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai.
Ṣàwárí II. Kro 20:21
5
II. Kro 20:22
Nigbati nwọn bẹ̀rẹ si ikọrin ati si iyìn, Oluwa yàn ogun-ẹhin si awọn ọmọ Ammoni, Moabu ati awọn ara òke Seiri, ti o wá si Juda, a si kọlù wọn.
Ṣàwárí II. Kro 20:22
6
II. Kro 20:3
Jehoṣafati si bẹ̀ru, o si fi ara rẹ̀ si ati wá Oluwa, o si kede àwẹ ja gbogbo Juda.
Ṣàwárí II. Kro 20:3
7
II. Kro 20:9
Bi ibi ba de si wa, bi idà, ijiya tabi àjakalẹ-àrun, tabi ìyan, bi awa ba duro niwaju ile yi, ati niwaju rẹ, (nitori orukọ rẹ wà ni ile yi): bi a ba ke pè ọ ninu wàhala wa, nigbana ni iwọ o gbọ́, iwọ o si ṣe iranlọwọ.
Ṣàwárí II. Kro 20:9
8
II. Kro 20:16
Lọla sọ̀kalẹ tọ̀ wọn: kiyesi i, nwọn o gbà ibi igòke Sisi wá; ẹnyin o si ri wọn ni ipẹkun odò na, niwaju aginju Jerueli.
Ṣàwárí II. Kro 20:16
9
II. Kro 20:4
Juda si kó ara wọn jọ, lati wá iranlọwọ lọwọ Oluwa: pẹlupẹlu nwọn wá lati inu gbogbo ilu Juda lati wá Oluwa
Ṣàwárí II. Kro 20:4
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò