1
JAKỌBU 4:7
Yoruba Bible
YCE
Nítorí náà, ẹ fi ara yín sábẹ́ àṣẹ Ọlọrun. Ẹ dojú ìjà kọ Èṣù, yóo sì sálọ kúrò lọ́dọ̀ yín.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí JAKỌBU 4:7
2
JAKỌBU 4:8
Ẹ súnmọ́ Ọlọrun, òun óo sì súnmọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ jẹ́ kí ọkàn yín dá ṣáká, ẹ̀yin oníyèméjì.
Ṣàwárí JAKỌBU 4:8
3
JAKỌBU 4:10
Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Oluwa, yóo wá gbe yín ga.
Ṣàwárí JAKỌBU 4:10
4
JAKỌBU 4:6
Ṣugbọn oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fi fúnni tóbi ju èyí lọ. Nítorí èyí ni Ìwé Mímọ́ ṣe sọ pé, “Ọlọrun lòdì sí àwọn onigbeeraga, ṣugbọn ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”
Ṣàwárí JAKỌBU 4:6
5
JAKỌBU 4:17
Nítorí náà, ẹni tí ó bá mọ rere í ṣe tí kò ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni ó ń gbà.
Ṣàwárí JAKỌBU 4:17
6
JAKỌBU 4:3
Bí ẹ bá sì bèèrè, ẹ kò rí ohun tí ẹ bèèrè gbà nítorí èrò burúkú ni ẹ fi bèèrè, kí ẹ lè lo ohun tí ẹ bèèrè fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara yín.
Ṣàwárí JAKỌBU 4:3
7
JAKỌBU 4:4
Ẹ̀yin àgbèrè, ẹ kò mọ̀ pé ìbá ayé ṣọ̀rẹ́ níláti jẹ́ ìbá Ọlọrun ṣọ̀tá? Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ti yàn láti jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun.
Ṣàwárí JAKỌBU 4:4
8
JAKỌBU 4:14
Ẹ kò mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ si yín lọ́la. Nítorí ìkùukùu ni yín, tí ó wà fún àkókò díẹ̀, lẹ́yìn náà tí kò ní sí mọ́.
Ṣàwárí JAKỌBU 4:14
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò