1
ISIKIẸLI 4:4-5
Yoruba Bible
YCE
“Lẹ́yìn náà, fi ẹ̀gbẹ́ rẹ òsì dùbúlẹ̀, kí o sì di ìjìyà àwọn ọmọ ilé Israẹli lé ara rẹ lórí. O óo ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún iye ọjọ́ tí o bá fi dùbúlẹ̀. Mo ti fún ọ ní irinwo ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390) láti fi ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli. Èyí ni iye ọdún tí wọ́n fi dẹ́ṣẹ̀.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí ISIKIẸLI 4:4-5
2
ISIKIẸLI 4:6
Nígbà tí o bá parí iye ọjọ́ yìí, o óo fi ẹ̀gbẹ́ rẹ ọ̀tún lélẹ̀, o óo sì fi ogoji ọjọ́ ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Juda; ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tí o óo fi dùbúlẹ̀ dúró fún ọdún kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fi dẹ́ṣẹ̀.
Ṣàwárí ISIKIẸLI 4:6
3
ISIKIẸLI 4:9
“Mú alikama ati ọkà baali, ẹ̀wà ati lẹntili, jéró ati ọkà sipẹliti, kí o kó wọn sinu ìkòkò kan, kí o sì fi wọ́n ṣe burẹdi fún ara rẹ. Òun ni o óo máa jẹ fún irinwo ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390), tí o óo fi fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀.
Ṣàwárí ISIKIẸLI 4:9
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò