Ọlọrun Israẹli ti sọ̀rọ̀,
Àpáta Israẹli ti wí fún mi pé,
‘Ẹni yòówù tí ó bá fi òtítọ́ jọba,
tí ó ṣe àkóso pẹlu ìbẹ̀rù Ọlọrun,
a máa tàn sí wọn bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,
bí oòrùn tí ó ń ràn ní òwúrọ̀ kutukutu,
ní ọjọ́ tí kò sí ìkùukùu;
ó dàbí òjò tí ń mú kí koríko hù jáde láti inú ilẹ̀.’