← Àwon ètò
Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Rut 4:14

Rúùtù
4 Awọn ọjọ
Ètò kíkà ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí jẹ́ awílé fún ìwé Rúùtù, ó sì ń ṣe àfihàn ìjólótìítọ́, ìwàláàyè, ìràpadà, àti àánú Ọlọ́run. Tí o bá rò pé o ti sọnù, tàbí o wà lẹ́yìn odi tí ò ń yọjú wọlé, ìtàn Rúùtù yóó ru ọ́ sókè, yóó sì gbé ẹ̀mí rẹ ró láti rán ọ létí pé Jésù, Olùràpadà wa tú oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ jade sórí àwọn tí wọ́n rẹ ara wọn sílẹ̀.

Rúùtù: Ìtàn Ìràpadà ìfẹ́ Ọlọ́run
Ọjọ́ 7
Bóyá ọ̀kan l'ára àwọn ìtàn kúkúrú tí ó wunilori jù lọ, ní ìwé Rúùtù tí ó jẹ́ àkọsílẹ̀ ti ìràpadà ìfẹ́ Ọlọ́run. Iwe Rúùtù jẹ́ ìtàn tí ó yanilẹ́nu bí Ọlọ́run ṣe nlo ìgbésí ayé àwọn ènìyàn lásán láti ṣe iṣẹ́ ìfẹ́ Òun ti o jé Ọba Aláṣẹ. Pẹ̀lú àwọn àkàwé tí ó rẹwà ti ìfẹ́ àti ìrúbọ Krístì fún àwọn ènìyàn Rẹ, a fi hàn wá ipele tí Ọlọ́run lọ láti ra àwọn ọmọ Rẹ̀ padà.