Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Rom 8:37

Ìrètí Ìyè: Ìfojúsọ́nà fún Àjíǹde
Ọjọ́ Mẹ́ta
Nígbà tí òkùnkùn bá bò ọ́ mọ́lẹ̀, irú ìhà wo ló yẹ láti kọ? Ri araà rẹ sínú ìtàn ọdún àjíǹde ní ọjọ́ mẹ́ta tó ń bọ̀, pàápàá ní àwọn àkókò tí ó bá ńṣe ọ́ bíi wípé a ti kọ̀ ẹ́ sílẹ̀, tàbí wípé a kò kà ọ́ yẹ.

Líla Ìgbà Ìṣòro Kọjá
Ọjọ́ Mẹ́rin
A kò lè fẹ́ àwọn ìdojúkọ kù nínú ayé wa. Ṣùgbọ́n nínú Ètò kúkúrú ọlọ́jọ́-4 yìí, a ó máa gbà wá ní ìyànjú láti mọ̀ pé a kò dá nìkan wà, pé Ọlọ́run ní ète fún ìrora wa, àti pé yíó lò ó fún ètò gíga Rẹ̀.

Ọlọrun, Èmi Ńkọ́?
Ọjọ marun
Nígbà tá a bá rò pé a ti jìnnà síbi tá a yẹ ká máa gbé, tí ohùn ìfiwéra sì túbọ̀ ń dún bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, a kì í sábà rí i pé Ọlọ́run wà láàárín wa. Àwọn àkókò yìí gan-an ni ìgbàgbọ́ wa máa ń lágbára jù lọ. Ka àdúrà yìí kó o sì rí ìṣírí gbà bó o ṣe ń dúró de Ọlọ́run.

Dìde kí o tan ìmọ́lẹ̀
Ọjọ́ 5
Àwọn ènìyàn maá ń sọ ní ọ̀pọ̀ ìgbà pé, "Kó gbogbo àníyàn rẹ tọ Ọlọ́run." Ṣé o tilẹ̀ ròó rí pé: Báwo ni mo ṣe lè ṣe èyí? Ìdíbàjẹ́ inú ayé ka 'ni l'áyà. Bí ó sì ti lè wù ọ́ tó láti tan ìmọ́lẹ̀ Jésù, ìwọ yíó máa wo òyé bí èyí yíó ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀ nígbàtí ìwọ alára ń tiraka láti rí ìmọ́lẹ̀ yìí fún ara rẹ. Ẹ̀kọ́ ìfọkànsìn yìí ṣe àgbéyẹ̀wò bí a ṣe lè jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún Jésù nígbàtí ayé tiwa gan-an dàbí pé ó wà ní òkúnkùn.

Ìhùwàsí
Ọjọ́ 7
Báwo ní a ṣe lè hu ìwà tí ó yẹ nínú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀? Kí gan-an ni ìwà tí ó yẹ? Ètò Bíbélì ọlọ́jọ́-méje yìí wá ìdáhùn jáde nínú ìgbé-ayé àti ẹ̀kọ́ Krístì. Jẹ́ kí àwọn ìsítí ojoojúmọ́ yìí, àwọn àṣàrò àdúrà, àti àwọn ésẹ Ìwé-mímọ́ alágbára ṣe ẹ̀dà ọkàn Krístì ní inú rẹ.

Mí Ìdí Tẹ̀mí Sínu Ìgbéyàwó Rè
7 ọjọ
A mu láti ìwé tuntun rè " Ifé Ayègígùn," Gary Thomas sọ̀rọ̀ sínu àwon ìdí ayérayé ti ìgbéyàwó. Kọ̀ọ́ practical ohun èlò láti ìrànlọ́wọ́ siṣẹ́ ọnà ìgbéyàwó rè sínu ìbáṣepò onímìísí, to n tànkálẹ̀ ìgbé-ayé tẹ̀mí si àwọn ẹlòmíràn.

Ara Èké
7 Awọn ọjọ
Ǹjẹ́ àwọn ìbẹ̀rùbojo ati àìláàbò ayéè rẹ ti tì ọ́ sínú ìdánimọ̀ tó ṣe àjèjì? Kíni ìwọ̀n ìyàtọ̀ tó wà ní àárín ẹni tí ìwọ jẹ́ ní òtítọ́ àti àwòrán rẹ tí o fi ń han àwọn míràn? Ní ìbásepọ̀ pẹ̀lú LUMO àti OneHope, àti tó dá lórí ìwàásù Àlùfáà Tyler Staton, ètò ọlọ́jọ́ méje yí yóò mú ẹ ṣe àyẹ̀wò òtítọ́ kodoro tó wà lẹ́yìn “ara èké.