← Àwon ètò
Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú O. Daf 5:3

Àgbàrá Ìyìn Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀: Ètò Ìfọkànsín Olóòjọ́ Márùn-ún Láti Inú Ìwé Orin Dáfídì
Ọjọ́ Márùn-ún
Àníyàn, ìfọ̀yà, ìdánìkanwà àti ìsoríkó tí dìde gidi gàn láàárín ọdún mélòó kan tó kọjá. Àwọn èrò ìmólárá wonyìí kìí ṣe tuntun si àwọn Onísáàmù. Àmó, wón kó láti tú àgbàrá ìyìn tó ṣàrà ọ̀tọ̀ jáde láti bórí. Ṣàwárí àṣírí láti fọkàn rẹ̀ balẹ̀ nínú àwọn ìfọkànsin yìí láti ìwé Orin Dáfídì.

Àdúrà
Ọjọ́ Mọ́kànlé-Lógún
Kọ́ bí ó ṣe dára jùlọ láti gbàdúrà, láti inú ádùrá àwọn olódodo àti láti àwọn ọ̀rọ̀ Jésù fún rara Rẹ̀. Wá ìwúrí láti máa mú àwọn ìbéèrè rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run l'ójoojúmọ́, pẹ̀lú ìtẹramọ́ṣẹ́ àti sùúrù. Ṣ'àwárí àwọn àpẹẹrẹ ádùrá òfo, òdodo ti ara ẹni, èyí tí ó ṣe déédé sí àwọn ádùrá mímọ́ ti àwọn tí ó ní ọkàn mímọ́. Gbàdúrà nígbà gbogbo.