Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú O. Daf 19:1

Nígbàtí Ìgbàgbọ́ Bá Kùnà: Ọjọ́ Mẹ́wàá Nípa Wíwá Ọlọ́run Nínú Òjìji Iyèméjì
Ojó Méwàá
Ìlàkàkà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti iyèméjì jẹ́ ohun tí ó lè jẹ́kí ènìyàn fẹ́ dáwà tàbí kí ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Àwọn kàn ńdá jìyà láìjẹ́ kí enìkankan mọ̀, àwọn míràn kọ ìgbàgbọ́ sílẹ̀ lápapọ̀, wọ́n rò pé iyèméjì kò ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Dominic Done gbàgbọ́ wípé èyí jẹ́ àsìse àti oun tí ó bani lọ́kàn jẹ́. Ó lo Ìwé mímọ́ àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ láti jiyàn wípé bíbèèrè nípa ìgbàgbọ́ bójúmu àti wípé ó sábà máa ńjẹ́ ọ̀nà síhà ìgbàgbọ́ tí ó lọ́rọ̀ àti tí ó lárinrin. Yẹ ìgbàgbọ́ àti iyèméjì wò nínú ètò ọlọ́jọ́ mẹ́wàá yìí.

KÉRÉSÌMESÌ: Ìmúṣẹ Ètò Ìdáǹdè Ọlọ́run
Ọjọ́ Mẹ́rìnlá
Àwọn òrìṣà èké tí àwọn ènìyàn mọ láti fi ṣe àpèjúwe òrìṣà kan tí wọ́n mọ̀ pé ó ní láti wà, kò ya'ni l'ẹ́nu pé, wọ́n jọ àwa ènìyàn gan-an. Wọ́n ní láti fi ìfọkànsìn mú wọn, kí wọ́n sì fún wọn ní rìbá kí wọ́n lè ṣe àkíyèsí wa. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà ti gbé ìgbésẹ̀, ó sì ń wá wa kiri––láti gbà wá padà sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀. Èyí gan-an ni ìtàn Kérésìmesì.